Wọn ti ko mọkanlelogoje ọmọ Naijiria to n gbe Libya pada sile - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 29, 2023

Wọn ti ko mọkanlelogoje ọmọ Naijiria to n gbe Libya pada sile


Ijọba orileede Naijiria pẹlu ajọṣepọ ajọ kan ti wọn pe ni International Organization for Migration (IOM) ti ko awọn ọmọ orileede naa to n gbe lorileede Libya pada sile lati bẹrẹ igbesi aye tuntun.

Nnkan ko fararọ f'awọn ọmọ Naijiria naa to wa ọjọ iwaju rere lọ si Libya, lo fa a ti ijóba apapọ fi dide lati lọ ko wọn pada wa sile.
 
Gẹgẹ bi Ambasidọ Kabiru Musa, to jẹ aṣoju orileede Naijiria nilẹ Libya, iyẹn Charge D’affaires of the Nigerian Mission in Libya, nigba to n sọrọ niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii sọ pe awọn eeyan naa lọ fara wọn sile lati pada wa sile.
 
O ni lati ilu Benghazi ni Libya ni baluu wọn ti gbera, to si ko obinrin mọkanlelaadọrin; ọkunrin mẹrinlelaadọta; ọmọde mẹrinla ati ọmọ ọwọ mẹtala.
 
Papakọ ofurufu ti Murtala Muhammed lawọn eeyan naa de si, iyẹn nibi ti baluu wọn balẹ si.
 
Musa ni ẹgbẹrun mẹrin ọmọ Naijiria ni ijọba ai ajọ naa ko pada wa si Naijiria lati Libya kan naa yii, nitori pe nnkan to ri bo ṣe yẹ fun wọn, eyi to jẹ ki wọn ke gbajare, iyẹn lọdun 2022.
 
Bakan naa lo sọ pe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, awọn tun ko ipele akọkọ awọn eeyan naa wa si Naijiria, to si lawọn miran ṣi n bọ.
 
O wa jẹ ko di mimọ pe ọna aitọ lawọn ọmọ Naijiria ọhun n gbe ilẹ Libya, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI