Ọmọ 'Yahoo' mọkanlelogun wọ gau l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 17, 2023

Ọmọ 'Yahoo' mọkanlelogun wọ gau l'Abuja


Ko din ni mọkanlelogun afurasi ọmọ Yahoo tọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC niluu Abuja, ti wọn si ti wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo.

Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 2023 ti a wa yii ni ajọ EFCC sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn gendekunrin naa ti wọn niṣẹ meji ju iwa jibiti ori ayelujara lọ.

Awọn afurasi naa; Joseph Boniface, Emmanuel Okwara, Elijah Iwebie, Moses Hassan, Abdulrahman Lawal, Azu Chidubem Eugene, Abdullahi Adebola ati Elijah Simon.

Awọn yooku ni Terfa Lincoln, David Kome, Chukwudah Martinez, Adie Matthew, Canice Agabi, Abbas Aminu, Damilare James and Christopher Simon. Also arrested include Mohammed Abdulhamid, Ifeanyi Bosah, Ayuba Aminu, Godwin Terkura ati Victor Ademola.

Wọn ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Lugbe ati Kubwa niluu Abuja lọwọ ti tẹ gbogbo wọn.
 
Foonu olowo nla, iPhone marundinlọgbọn; kọmputa alagbeeka mẹta, ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes CLA250 ati C300 ni wọn gba lọwọ wọn, gẹgẹ bi EFCC ṣe ṣalaye.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI