Mo ti sọ f'awọn oloye mi wi pe wọn ko gbọdọ yọ nnkan lara mi, bi mo ba ku - Ọṣilẹ Oke-Ọna Egba, Ọba Tẹjuoṣo pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 17, 2023

Mo ti sọ f'awọn oloye mi wi pe wọn ko gbọdọ yọ nnkan lara mi, bi mo ba ku - Ọṣilẹ Oke-Ọna Egba, Ọba Tẹjuoṣo pariwo sita


Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo ti pariwo sita wi pe oun ti ṣe ikilọ f'awọn oloye aafin oun lati ma ṣe yọ ẹya ara oun kankan kuro lẹyin toun ba lọ sibi agba n re, iyẹn toun ba waja.
 
Kabiyesi naa lo sọrọ yii lakoko to n ba BBC YORUBA sọrọ ni Aafin rẹ to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Ọba Tẹjuoṣo sọ pe gbogbo awọn oriṣa Ọbatala to wa laafin oun, paapaa eyi ti ilu Oke-Ọna Ẹgba n sin loun ti ko kuro, toun si ti gba Ọlọrun laaye, fun idi eyi, o loun ko ni nnkan ṣe pẹlu oriṣa kankan mọ.
 
F'awọn to ba mọ Ọba Tẹjuoṣo daadaa, ọdọọdun lo maa n ṣayẹyẹ orin iyin to pe ni 'Kings Day of Praise', lati maa fi yin Ọlọrun rẹ logo, eyi to maa n sunmọ ayẹyẹ ọjọ ibi ẹ.
 
O ni pupọ awọn nnkan to n ṣẹlẹ lorileede Naijiria lasiko yii lo jẹ pe nitori ai sunmọ Ọlọrun ni, ati pe ai kii ka bibeli deedee ni, to si ni k'awọn eeyan lọ maa ka iwe Owe, ori kinni, ẹsẹ kẹrinlelogun.

Nibẹ lo ti sọ pe Ọlọrun ti pe gbogbo awọn eeyan, ṣugbọn ti wọn ko gbọ, to si loun yoo fi wa silẹ. Bẹẹ ni Ọlọrun sọ pe ti iṣoro ba de ba ẹda, oun yoo jokoo ni ọrun lati maa rẹrin.

“Ki lan ṣe bayii? Njẹ ẹ n gbadun aye? Niṣe la n jiya nigba ti Ọlọrun ti pe wa, ṣugbọn a ko daa lohun. Nigba ti a yan Ọbatala to jẹ eeyan, ti a si bẹrẹ sii sin in. Bẹẹ naa la bẹrẹ sii sin Ṣango, ẹni to sọrọ rẹ si ọlọrun kekere.

“Oriṣa kii ṣe nnkan ti mo le parun patapata, mo kan le koo kuro fun awọn eeyan to yi mi ka ni. Iyẹn to ba ṣee ṣe lati gbọ ọrọ Ọlọrun.”

“Mo ti sọ fun awọn oloye mi wi pe bi mo ba waja, ẹnikẹni to ba ṣe etutu ketutu si ara mi yoo gba Ọlọrun l'ọga.

“Bi wọn ba si fẹẹ yan ọba miran, wọn gbọdọ ṣee ni ilana ẹsin ti iru ọba bẹẹ ba yan laayo. Bi wọn ba si fẹẹ sin ọba bẹẹ, wọn gbọdọ sin in nilana ẹsin rẹ pẹlu ohun ti awọn mọlẹbi rẹ ba fẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI