Ọwọ tẹ gbajumọ Aafa Ilọrin ati awọn ibeji to n ṣe 'Yahoo-Yahoo' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, March 24, 2023

Ọwọ tẹ gbajumọ Aafa Ilọrin ati awọn ibeji to n ṣe 'Yahoo-Yahoo'


Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati jibiti ori ayelujara, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, l'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ti kede sita wi pe ọwọ awọn ti tẹ gbajugbaja Aafa kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo'.
 
Yatọ si Aafa naa tọwọ tẹ, ọwọ tun tẹ awọn mẹtadinlọgbọn miran lori ẹsun jibiti ori ayelujara kan naa.

Agbegbe ti wọn n pe ni Mandate lọwọ ti tẹ awọn afurasi naa, lẹyin olobo to ta ajọ naa lọwọ.
 
Bakan naa la tun gbọ pe ọwọ tẹ awọn ibeji, to fi mọ awọn akẹkọọ, ati oniṣẹ ọwọ.
 
Aafa naa, Tọheeb Albarka,; Lambẹ Kẹhinde ati Lambẹ Taye, ti wọn jẹ ibeji; Francis Stephen, Ọlabọde Yusuf, Musbaudeen Akorede, Adedamọla Samson, Ọlarewaju Adisa Taofeek, Adewale Oloro.
 
Agboọla Marvellous, Adebisi Ọlatunde, Moshood Okunọla, Kayọde Aderẹmi, Ayọbami Ọlọrunfẹmi ati Paul Ayọmide ni wọn jẹ akẹkọọ tọwọ palaba wọn segi.
 
Bakan naa lọwọ tun tẹ Ọlalẹyẹ Solomon, Akinade Samuel, Damilọla Shagaya, Muhammed Awal, Adam Mubarak, Ogundiran Nathaniel, Jamiu Iṣhọla, Dauda Tunde, Abdullahi Sikiru, Afeez Adegoke, Jordan Adeyinka, Ọjeniyi Boluwatifẹ ati Ọmọgbọlahan Ibrahim.
 
Wilson Uwujaren to jẹ agbẹnusọ fun ajọ EFCC ti ṣalaye pe gbogbo wọn lo ti jẹwọ, ati pe awọn gba ọkọ bọginni, ẹrọ kọmputa alegbeeka ati awọn nnkan miran ti wọn fi n ṣiṣẹ jibiti wọn.
 
O wa sọ pe wọn yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI