Ẹ jawọ ninu tẹtẹ lati gbajumọ aawẹ Ramadaani - Naira Marley gb'awọn Musulumi lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, March 25, 2023

Ẹ jawọ ninu tẹtẹ lati gbajumọ aawẹ Ramadaani - Naira Marley gb'awọn Musulumi lamọran


Gbajugbaja olorin takasufee nni, Azeez Faṣhọla, ẹni t'ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Naira Marley ti gba gbogbo awọn Musulumi, paapaa awọn to fẹran lati maa ta tẹtẹ lati jawọ kuro nidii iwa naa, ki wọn si gbajumọ aawẹ Ramadaani to wa nita lasiko yii.
 
Ori ikanni ayelujara ti Twitter ni Naira Marley ti gba awọn Musulumi yii lamọran, to si ni ki wọn bọwọ fun aawẹ Ramadaani, paapaa Allah to fun wa lanfaani lati ri asiko aawẹ yii.

Siwaju sii lo ni ki wọn dẹkun tẹtẹ ere bọọlu, nitori pe oṣu ti awọn eeyan gbọdọ kọ eṣu, ẹṣẹ ati iṣẹ ọwọ rẹ silẹ ni, nitori pe oṣu mimọ ni.
 
Ninu ọrọ to kọ sita naa, o ni 
"Arakunrin, gbagbẹ ọọdi to da ẹ loju yẹn, ki o si gbagbe tẹtẹ...gba aawẹ 🙏

“Oṣu Ramadaani jẹ eyi Kuraani ran wa gẹgẹ bi ipilẹ mimọ lati daabo bo ẹda eniyan. Ninu rẹ ni ẹkọ to ye kooro, ati ilana idajọ ninu ododo.’ Noble Quran 2:185.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI