Tẹgbọn-taburo to n ṣe Yahoo-Yahoo ha l'Ẹdo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 22, 2023

Tẹgbọn-taburo to n ṣe Yahoo-Yahoo ha l'Ẹdo


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajebanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ti rọwọ to tẹgbọn taburo kan ti wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara lọ.
 
Ilu Benin to wa nipinlẹ Ẹdo lọwọ palaba wọn ti segi, lẹyin olobo to ta ajọ naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Wilson Iwujaren to jẹ agbẹnusọ fun ajọ EFCC ṣalaye pe aarọ kutu lọwọ tẹ awọn afurasi naa ti wọn tun n pe ni Ọmọ Yahoo-Yahoo, to si ni mọkanlelogun ni gbogbo awọn tọwọ tẹ lẹẹkan naa.
 
O darukọ awọn tọwọ tẹ naa gẹgẹ bii Marvelous Alakpa, Kelly Alakpa, Barnabas Alakpa, Hoghomhen Jude Moses, Christopher Odion, Azanuwna Joseph, Godfirst Christopher.

Awọn miran ni Onus Honda, Junior Azanuwna, Ehis Inegbinebor Francis, Godbless Eriugo, Imokhai Dickson, Epama Francis, Ekuma Austin ati Sunday Stanley.

Awọn yooku ni Eghosa Osaretin, Amiole Paul, Iweriebor Raphael, Sunday Christian, Imozemhe Raymond ati Agbonghae Anthony.

O ni mọto mẹfa ọtọọtọ, bii Mercedes Benz meji, Lexus ES 350 meji, Lexus RX 330, ẹyọkan ati Toyota Camry ẹyọkan, to fi mọ ẹrọ kọmputa lagbeka HP loriṣiriṣi ati foonu olowo nla rẹpẹtẹ ni wọn gba lọwọ
 
Uwujaren fi ye wa pe gbogbo awọn tọwọ tẹ yii ni wọn ti jẹwọ, to si ni wọn ko ni pẹ ẹ foju ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI