Mo ti pari iṣẹ ti mo wa ṣe laye, mo maa ku laipẹ - Wolii Odumeje - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 21, 2023

Mo ti pari iṣẹ ti mo wa ṣe laye, mo maa ku laipẹ - Wolii Odumeje


Gbajugbaja Wolii nni to fi ilu Onitsha ni ipinlẹ Anambra ṣe ibugbe, Wolii Chukwuemeka Ohanere ti sọ pe asiko oun nile aye ti n to, oun ko si ni pẹ ẹ jade laye.

Wolii Ohanere ti ọpọ awọn eeyan tun n pe ni Wolii Odumeje, to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ The Mountain of Holy Ghost Intervention and Deliverance Ministry, to wa lagbegbe Fegge niluu Onitsha lo sọrọ naa laipẹ yii.

Nibi iwaasu to ṣe ninu ijọ rẹ lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni Wolii Odumeje ti sọ pe oun ti pari iṣẹ ti Ọlọrun ran oun wa ṣe nile aye, asiko si ti to lati pada sibi toun ti wa.

O loun ti ṣalaye fun awọn ọmọ oun lati maa mura silẹ fun iku oun, nitori pe igbakugba loun le jade laye.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
“Mo ti pe ọmọ mi, King David, mo si ti sọ fun un pe, emi baba rẹ yoo lọ laipẹ. O ni lati tọju awọn aburo rẹ ati mama yin.

“Mo wa sile aye yii fun idi kan ni pato ni, mo si ti pari iṣẹ ti mo wa ṣe. Mo ti pari iṣẹ iranṣẹ mi nile aye, mo si maa lọ laipẹ.”

Fawọn ti ko ba mọ Wolii Odumeje, oun ni gbajugbaja Wolii to maa n ṣiṣẹ iyanu lara ọtọ. Bi ko ba lu awọn ọmọ ijọ rẹ, ko nii ṣiṣẹ iyanu. Bo ba si ṣe n gun wọn lori, ni yoo maa ṣe wọn niṣekuṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI