Aami ẹyẹ ti a sẹsẹ gba jẹ ka mọ igbagbọ ti awọn ọmọ Naijiria ni ninu wa - Alaṣẹ Pelican Valley - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 16, 2023

Aami ẹyẹ ti a sẹsẹ gba jẹ ka mọ igbagbọ ti awọn ọmọ Naijiria ni ninu wa - Alaṣẹ Pelican Valley


Alaṣẹ, apaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited ti a mọ si Pelican Valley Estate, Ọjọgbọn Babatunde Adeyẹmọ ti sọ pe bi awọn eeyan ṣe dibo fun wọn gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ta ilẹ ati dukia to ṣe daadaa julọ lọdun 2022 ti fi han pe awọn araalu ni igbagbọ to tọ ninu wọn.

Ọjọgbọn Adeyẹmọ lo sọ eyi di mimọ ninu ọrọ idupẹ rẹ, lẹyin ti wọn kede ileeṣẹ Pelican Valley Estate wi pe awọn lo jawe olubori ninu idije to ṣẹṣẹ pari.

Ileeṣẹ iwe iroyin AMEBO NEWS HUB lori ayelujara ninu eto aami ẹyẹ ọlọdọọdun wọn, eyi ti wọn bẹrẹ l'ọsẹ to kọja, ni wọn ti mu ileeṣẹ Pelican Valley Estate mọ ara awọn ileeṣẹ to n ṣe daadaa lẹka okoowo ilẹ.

A gbọ pe ileeṣẹ ti ko din mejila ti wọn n ṣoowo ilẹ ni wọn wa ni ipele idije yii, eyi ti ileeṣẹ Pelican Valley Estate naa wa lara wọn.

Nigba to n sọrọ lonii, ọjọ Aiku, Sannde, Ọjọgbọn Adeyẹmọ sọ pe idunnu nla lo jẹ fun wi pe awọn ọmọ Naijiria dibo fún wọn, eyi ti wọn fi jawe olubori.

O ṣalaye pe idibo to waye naa fi han awọn araalu mọ nnkan to n lọ lagboole okoowo ile gbigbe kaakiri Naijiria, paapaa n'ipinlẹ Ogun.

Siwaju sii lo sọ pe eto idibo naa waye lai si magomago, nitori pe ori ayelujara ti gbogbo eeyan n wo bo ṣe n lọ lo ti waye.

Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun ileeṣẹ AMEBO NEWS HUB lori eto idibo ọlọdọọdun ti wọn fi n mọ riri awọn eeyan ati ileeṣẹ kaakiri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI