Abiọun yan akọwe agba mẹta l'Ogun, o tun gba wọon lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 4, 2023

Abiọun yan akọwe agba mẹta l'Ogun, o tun gba wọon lamọran


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti yan awọn akọwe agba mẹta lati di awọn aaye to ṣofo, to si ni ki iṣẹ wọn bẹrẹ loju ẹsẹ lai fi akoko ṣofo.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe bi wọn ṣe yan awọn eeyan naa lati di awọn ipo yii, ko ṣẹyin bi wọn ṣe pẹ lẹnu iṣẹ si, ati iriri wọn.

O lawọn ti wọn yan naa yẹ, nitori pe ipo to kọgun si ipo ọga ni wọn wa, wọn si jafafa daadaa nipa imọ, ọgbọn ati oye ohun ti wọn fẹẹ ṣe.
 
Awọnn ti wọn yan naa ni Ọgbẹni Ọlatunji Timothy Ayọọla to jẹ alakoso agba tẹlẹ ni ileeṣẹ to n ri sọrọ agbẹ (Director of Administration and Supplies, Ministry of Agriculture); Ọgbẹni Adeogun Samuel, to jẹ akọwe agba ni ẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ idagbasoke agbẹ (Director, Planning, Monitoring and Evaluation, Ogun State Agricultural Development Programme), ati Arabinrin Ọlọkọ Mọriamọ Oluwatosin toun naa jẹ alakoso agba nileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ (Director of Education, Ministry of Education, Science and Technology).

Ṣomọrin sọ pe Gomina Dapọ Abiọdun ti ki wọn ku oriire, bẹẹ lo si tun gba wọn lamọran lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣe fun igbega ati ilọsiwaju ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI