Ọkunrin to ni wọn ko gbọdọ bura fun Tinubu foju ba ile-ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 4, 2023

Ọkunrin to ni wọn ko gbọdọ bura fun Tinubu foju ba ile-ẹjọ


Ọgbẹni Obiajulu Uja to n pariwo ninu ọkọ baluu to n lọ lati Ekoo si Abuja lọsẹ to kọja wi pe ijọba orileede yii ko gbọdọ bura fun Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu to jawe olubori ninu eto idibo apapọ to waye loṣu keji ọdun yii gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria ti pada foju ba ile-ẹjọ.
 
Ile ẹjọ Majisireeti to wa ni Zuba niluu Abuja ni Uja foju ba, lori ẹsun to nii ṣe pẹlu pipe fun ogun.
 
Agbẹjọro rẹ, Ejike Ugwu lo sọrọ naa f'awọn akọroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
 
Uja lo dide ninu ọkọ baalu naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, to si bẹrẹ sii fẹhonu han pe wọn ko gbọdọ bura fun Tinubu gẹgẹ bi aarẹ Naijiria lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023.
 
Loju ẹsẹ ni wọn lawọn oṣiṣẹ aabo papakọ ofurufu ti ko din ni mẹfa ti dide lati wọ ọ bọ silẹ ninu baalu ọhun, eyi to mu ki baalu ọhun pẹ ko too gbera.
 
Ẹsun ti wọn fi kan Uja ni dida wahala silẹ, aijọwọ ara ẹni silẹ fun ijọba lati mu, idunkoko ipe fun ogun ati iwa to le da alaafia ilu ru, eyi ti wọn lo tako iwe ofin ti abala 396, 267,188,172 and 144.
 
Agbẹjọro naa sọ pe niṣe ni wọn tan awọn jẹ, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile ẹjọ. O ni ile iwosan ọlọpaa ti Muhammadu Buhari, eyi to wa lagbegbe Area 11 ni wọn kọkọ gbe Uja lọ fun ayẹwo.
 
O ni kii ṣe pe wọn ni awọn dokita to n ṣayẹwo ọpọlọ nibẹ lati yẹ ẹ wo, ṣugbọn ti wọn ranṣẹ si dokita kan ni ọsibitu apapọ l'Abuja, to si ni pabo ni gbogbo ayẹwo naa ja si.

Siwaju sii lo sọ pe nigba ti awọn wa ni ile iwosan ọhun, ni wọn wa ba wọn ni nnkan bi aago mẹta ọsan wi pe wọn fẹẹ foju rẹ ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI