Agunbanirọ to lu ọga ọlọpaa ni jibiti owo dero ile-ẹjọ n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 14, 2023

Agunbanirọ to lu ọga ọlọpaa ni jibiti owo dero ile-ẹjọ n'Ibadan


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti foju gendekunrin agunbanirọ kan, Ukenwa Ikechukwu ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan, ipinlẹ naa lori ẹsun jibiti.
 
Ọga ọlọpaa kan ti wọn pe orukọ rẹ ni ACP Modupẹ Ọkpaleke ni wọn sọ pe Ukenwa lu ni jibiti owo to to N235,000 naira, pẹlu ẹtanjẹ.
 
Wọn ni bi Ukenwa ṣe gba owo naa tan, lo ti na a, to si n fi oni da oni, ọla da ọla fun un.
 
Ẹsun jibiti ni wọn fi kan Ukenwa niwaju Onidajọ M. I. Giwa-Babalọla.
 
Ohun ti a gbọ ni pe Ọkpaleke lo ni ipenija ẹsẹ lọdun to kọja, ti wọn si lawọn kan lo juwe Ukenwa fun un, wi pe agunbanirọ to kẹkọọ nipa eto ilera, iyẹn physiotherapy ni, ati pe o wa lara awọn agunbanirọ ti wọn gbe wa si ọsibitu ileeṣẹ ọlọpaa, iyẹn Police Cottage Hospital, to wa lagbegbe Ẹlẹyẹle niluu Ibadan.
 
Agbefọba, Insp Olufẹmi Omilana, to fẹsun kan Ukenwa niwaju ile ẹjọ sọ pe nipa ẹtanjẹ lọmọkunrin naa fi gba owo ọhun lọwọ Ọkpaleke.
 
O ni ẹsun naa tako iwe ofin ọdaran ti abala 390 (9) ati 419 tipinlẹ Ọyọ, tọdun 2000.
 
Ninu ọrọ Onidajọ M. I. Giwa-Babalọla lo ti loun faaye beeli idaji miliọnu naira silẹ fun Ukenwa pẹlu oniduro meji ti wọn n san owo ori wọn deedee, bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ karundinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI