Gbajumọ pasitọ ijọ CAC to lu ayalegbe rẹ pa dero ọgba ẹwọn l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 14, 2023

Gbajumọ pasitọ ijọ CAC to lu ayalegbe rẹ pa dero ọgba ẹwọn l'Ondo


Ọkan lara awọn gbajumọ pasitọ ladugbo Moferere to wa lagbegbe Owe-Akala niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo, Emmanuel Adebayọ la gbọ pe ile ẹjọ ti ju satimọle lori ẹsun ipaniyan.
 
AWIKONKO gbọ pe Adebayọ, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta lo lu ọkan lara awọn ayalegbe rẹ to jẹ obinrin, Toyin Ọlatunji, ẹni aadọta ọdun lori ọrọ ti ko to nnkan.
 
Ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun ti a wa yii la gbọ pe Adebayọ ti wọn lo jẹ pasitọ ijọ Christ Apostolic Church lu obinrin naa pa ni ojule kẹrinla, adugbo Moferere, agbegbe Owe-Akala, niluu Akurẹ.
 
Abdulateef Suliaman to jẹ agbefọba nigba to n fẹsun kan Adebayọ ṣalaye pe ọrọ kan lo ṣebi ọrọ laaarin oun ati obinrin naa, to fi di pe Adebayọ tii lulẹ, tiyẹn si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Sulaiman ni ẹsun naa ti wọn fi tako Adebayọ lodi s'ofin ọdaran ti abala 310 ati 316 t'ipinlẹ Ondo, tọdun 2006.
 
O wa rọ ile ẹjọ lati paṣẹ pe ki Adebayọ ṣi wa lọgba ẹwọn lati gba amọran lọdọ alakoso eto idajọ, iyẹn Director of Public Prosecutions, DPP.
 
Onidajọ Tọpẹ Aladejana nigba toun naa n sọrọ paṣẹ pe Adebayọ ṣi wa lọgba ẹwọn Olokuta to wa nipinlẹ naa, titi di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI