Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ baba agbalagba, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta kan, Innocent Udoh to ji aadọrin foonu gbe, bẹẹ ni wọn lawọn ti foju rẹ ba ile ẹjọ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii ni Udoh foju ba ile ẹjọ Maijisireti to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan, ipinlẹ naa.
Gbogbo foonu naa ni wọn sọ pe owo to din diẹ ni miliọnu meji naira {N1.75 million}.
Nigba ti agbefọba, ASP Sikiru Ibrahim n ṣalaye fun ile ẹjọ, o ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ọgbọn ọjọ, oṣu kẹta, ọdun 2023 ni Udoh ji awọn foonu naa ni nnkan bi aago mejla si marun oru lagbegbe Mọkọla.
Aadọta foonu Itel ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin-le-laadọta naira, awọn foonu aloku ogun ti owo wọn ko din ni miliọnu kan naira ni wọn sọ pe Udoh jigbe.
O lawọn foonu naa lo jẹ ti Ọgbẹni Nwaoma Ezeco, to si ni ẹsun naa tako iwe ofin ọdaran tipinlẹ Ọyọ tọdun 2000 ni abala 516 ati 390(9).
Nigba to n sọrọ, Onidajọ Arabinrin T. B. Oyekanmi, sọ pe ki wọn gba beeli Udoh pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ati oniduro meji ti ile wọn ko jinna si ayika kootu naa.
Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun yii.
No comments:
Post a Comment