Peter to fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹsan laṣepọ dero ẹwọn gbere l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 1, 2023

Peter to fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹsan laṣepọ dero ẹwọn gbere l'Ekoo


Ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ọdaran to nii ṣe pẹlu ifipabanilopọ, iyẹn
Sexual Offences and Domestic Violence Court to wa niluu Ikẹja, ipinlẹ Ekoo ti ju olukọ kan, Peter Jacob sẹwọn gbere lori ẹsun ifipaba ọmọ ọdun mẹsan laṣepọ.

Iṣẹ olukọ ni wọn sọ pe Jacob f'ipa ja ibale ọmọ naa, ti wọn tun lo jẹ akẹkọọ rẹ.
 
Onidajọ Abiọla Ṣọladoye sọ pe awọn ẹri toun ri gba lori ẹsun ti wọn fi kan Jacob kọja ohun ti wọn le fọwọ bo, to si ni aridaju lawọn ẹri ọhun jẹ.
 
Ọdun 2019 la gbọ pe Jacob to n ṣiṣẹ olukọ ni ile ẹkọ Thescol College, CMD Road, Magodo, Ikẹja fipa ba ọmọ naa laṣepọ ninu ọgba ile ẹkọ ọhun, ti aṣiri rẹ si tu sita.
 
A gbọ pe ara ọmọ naa ko da pe daadaa, to si ni ipenija ara. Anfaani ohun to n ṣe ọmọ naa lo mu ki Jacob fipa ba a laṣepọ. Ẹsun ti wọn lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 137, tọdun 2015.
 
Onidajọ Ṣọladoye sọ pe ẹlẹrii mẹta ọtọọtọ ti wọn n ṣiṣẹ nile ẹkọ naa lo jẹri tako Jacob, toun naa ko si mọ ohun to le sọ mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI