Ẹ woju awọn afurasi ajinigbe to ji adajọ gbe ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 15, 2023

Ẹ woju awọn afurasi ajinigbe to ji adajọ gbe ni Kwara


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti foju awọn afurasi ti wọn lo ji adajọ ile ẹjọ Majisireeti,
Jumọkẹ Bamigboye gbe ninu oṣu kinni, ọdun yii lagbegbe Ẹyẹnkọrin niluu Ilọrin, ti wọn si gba owo ko to di pe wọn tuu silẹ.
 
Jumọkẹ ni iyawo alakoso eto iṣẹjọba ipinlẹ Bauchi ati Ọṣun labẹ iṣakoso ologun, ajagunfẹyinti, Col. Theophilus Bamigboye.
 
Nigba to n foju awọn afurasi mẹtalelogun tọwọ tẹ han f'awọn akọroyin niluu Ilọrin, l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Paul Ọdama ṣalaye pe nipa iranlọwọ awọn Fulani ati awọn ọlọdẹ lọwọ fi tẹ awọn afurasi naa.
 
O ni afurasi ajinigbe naa, Abubakar Shehu, ti wọn tun n pe ni Dogo ni olori awọn ajinigbe to ji Onidajọ Jumọkẹ Bamigboye.
 
Awọn yooku tọwọ tẹ tun ni Mohammed Aliyu, ẹni ọgbọn ọdun (30); Yunusa Ahmadu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28); Malami Usman, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), ati Dauda Amọsa, toun naa jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28).
 
Ọdama tẹsiwaju pe iwadii kikun t'awọn tun ṣe fidi rẹ mulẹ pe Dogo wa lara awọn to ji Alaaji Madaki Shaibu gbe ni gbagede awọn Fulani ti Ayegun ninu oṣu kinni, ọdun yii, to si ni wọn pada ṣeku pa Alaaji naa.
 
Bakan naa lo tun foju awọn mẹjọ miran, Habeeb Ayọmide, Oni Ọbasanjọ, Mohammed Abdulkareem, Ibrahim Apẹtẹ, Ajao Musa, Ismail Ayọmide, Adebayọ Abdulateef ati Yusuf Najeem lori ẹsun oogun owo.
 
Lara awọn nnkan to lawọn gba lọwọ wọn ni iṣasun ibilẹ to ni asejẹ ninu, kanrinkan, asọ etutu ati foonu nla kan.
 
O lawọn tọwọ tẹ yii, iṣẹ jibiti ori ayelujara ti wọn n pe ni Yahoo-Yahoo ni wọn fi n boju, lai mọ pe oogun owo ni wọn n ṣe kaakiri, to si ni gbogbo awọn tọwọ tẹ naa ni yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI