Nitori ko fẹẹ san owo ina, iyaale ile ja oṣiṣẹ IBEDC bọ lori opo-ina, niyẹn ba kan lẹsẹ l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 15, 2023

Nitori ko fẹẹ san owo ina, iyaale ile ja oṣiṣẹ IBEDC bọ lori opo-ina, niyẹn ba kan lẹsẹ l'Abẹokuta


Ariwo 'ikunlẹ abiyamọ' lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Olomore niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba ti iyaale ile, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Nọimọt Alalade ja oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna, iyẹn IBEDC bọ lori akaba to fi gun opo ina, tiyẹn si gbabẹ kan lẹsẹ.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna ni wọn lọ si agbegbe Olomore lati lọ gba owo ina t'awọn eeyan lo nibẹ, ati lati wo o boya ko sẹni to ji ina lo.
 
Wọn ni bi wọn ṣe ile Nọimọt to wa ni ojule karun-un, adugbo Amadiya to wa ni Olomore ni wọn beere pe awọn fẹẹ ri iwe to fi n san owo ina, ṣugbọn ti wọn ni ko da wọn lohun.
 
Kaka ko tun da wọn lohun, wọn ni eebu lo n bu wọn. Idi ree ti wọn fi sọ pe ọga to lewaju awọn oṣiṣẹ naalọ paṣẹ pe ki wọn ge ina to wọnu ile Nọimọt loju ẹsẹ.

Wọn ni bi Silas Ọlalẹyẹ to n tẹle wọn lati ge ina ṣe gun ori opo lati tẹle aṣẹ naa, ni Nọimọt lọ yẹ akaba mọ-ọn lẹsẹ, tiyẹn si jabọ lulẹ. Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe ẹsẹ Silas ti kan, to si tun farapa yannayanna.
 
Nibẹ ni wọn ti ranṣẹ s'awọn ọlọpaa, ti wọn si lọ gbe obinrin naa lati foju rẹ ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokuta, iyẹn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
 
Agbefọba Ọlaide Rawlings to fẹsun kan Nọimọt niwaju ile ẹjọ sọ pe ẹsun ti wọn fi kan obinrin naa tako iwe ofin ọdaran t'ipinlẹ ni awọn abala 338, 343, 355 ati 249, tọdun 2006.
 
Wọn sọ pe niwaju ile ẹjọ  ni Nọimọt ti ṣalaye pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun pẹlu alaye.
 
Onidajọ M.O. Ọsinbajo ninu ọrọ rẹ sọ pe anfaani wa lati gba beeli Nọimọt pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, ati oniduro kan ṣoṣo, to si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI