Gbajumọ aṣoju-sofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ku s'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 22, 2023

Gbajumọ aṣoju-sofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ku s'Abuja


Adura ti awọn eeyan maa n gba wi pe 'ogo de, ẹmi pin, ko ma ṣe jẹ ti wa', ni ko gba rara fun ọkan lara awọn oludije to jawe olubori s'ile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, lati ẹkun Jalingo/Yorro/ Zing Federal Constituency, ipinlẹ Taraba, Ọnarebu Isma’ila Yushua Maihanchi, lori bo ṣe ku siluu Abuja.
 
Aarọ oni, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide la gbọ pe Ọnarebu Maichanchi ku si ọsibitu kan ti a fi orukọ bo laṣiri, eyi to wa niluu Abuja, olu-ilu orileede Naijiria.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aisan ranpẹ kan ni wọn lo kọlu ọkunrin naa, to fi dero ọsibitu, ko to di pe ẹlẹmi gba a.
 
Amugbalẹgbẹ oloogbe naa ti fidi rẹ mulẹ pe oni yii naa ni wọn yoo sinku ọga oun si itẹku apapọ to wa niluu Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI