Wọn ju Kẹhinde sẹwọn gbere l'Ekoo, ọmọ ọdun mẹta lo fipa ja ibale rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 21, 2023

Wọn ju Kẹhinde sẹwọn gbere l'Ekoo, ọmọ ọdun mẹta lo fipa ja ibale rẹ


Ile ẹjọ to n gbọ ẹsun iwa ipa ati ifipabanilopọ nipinlẹ Ekoo, Lagos Sexual Offences & Domestic Violence Court to wa niluu Ikẹja ti ju Kẹhinde Gabriel sẹwọn gbere lori ẹsun ifipabanilopọ.
 
Ọmọ ọdun mẹta ni ile ẹjọ naa sọ pe Kẹhinde fipa ja ibale rẹ danu.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Ramon A. Oshodi sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Kẹhinde, eyi ti nọmba rẹ jẹ ID/8392C/2018 fidi rẹ mulẹ pe otitọ ni, to si gbọdọ jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofin.
 
O ni ẹri to kọja sisọ, eyi ti ko ṣee gboju fo da, to si gbọdọ foju winna ofin gẹgẹ bo ti tọ, ati bo ti yẹ ni abala 137 ti iwe ẹsun ọdaran ipinlẹ Ekoo, tọdun 2015.
 
Onidajọ Oshodi sọ pe wọn yoo kọ orukọ Kẹhinde sinu iwe ọdaran to nii ṣe pẹlu ibalopọ, iyẹn Sexual Offenders Register, eyi ti ijọba Ekoo n mojuto.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI