Ikunlẹ abiyamọ o! Hassan dana sun ololufẹ rẹ tẹlẹ l'Ogun, o loun ko le jẹ ko ba ẹlomiran lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 9, 2023

Ikunlẹ abiyamọ o! Hassan dana sun ololufẹ rẹ tẹlẹ l'Ogun, o loun ko le jẹ ko ba ẹlomiran lọ


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Yusuf Hassan, ẹni ọdun mẹtalelogoji ti wọn loo pa ololufẹ rẹ to n fẹ tẹlẹ, Busayọ Falọla.
 
Kii ṣe pẹ Hassan pa Busayọ lasan, wọn ni niṣe lo dana sun un mọ inu le tiyẹn gbe loru ọganjọ, iyẹn lakoko ti igbogbo eeyan ti lọ sun.
 
AWIKONKO gbọ pe ojule 127, adugbo Scholar Palace to wa lopopona Igan, Agọ Iwoye ni iṣẹlẹ naa ti waye, iyẹn nibi ti oloogbe naa n gbe.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni nnkan bi aago kan kọja iṣẹju mẹẹdogun oru ni Hassan yọ wọ inu ọgba ile ti Busayọ n gbe, to si gbe epo pẹtiroolu to ra ni ẹẹdẹgbẹta naira dani.

A gbọ pe bo ṣe wọnu ọgba ile naa, lo gba oju ferese yara ti Busayọ n gbe lọ, to si da pẹtiroolu naa sinu yara ọhun, ko to di pe o sare ṣa ina sii. Bo si ṣe ṣa ina sii, lo na papa bora, lai jẹ kẹnikẹni mọ.

Gbogbo asiko yii, Hassan ko mọ pe ẹnikan n wo oun. Wọn ni ọkan lara awọn araale lo ri Hassan nigba to n da pẹtiroolu sinu yara ololufẹ rẹ tẹlẹ, ṣugbọn nipa ibẹrubojo ni ko fi sọrọ.
 
Ẹni naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Falọla Busayọ ni wọn lo sọ pe nnkan bi aago mejila aabọ oru loun ri Hassan lakoko to n ṣe ijamba naa, ṣugbọn toun ko mọ pe bi yoo ṣe to niyẹn.
 
Ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun yii ni iṣẹlẹ naa waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi nigba to n sọrọ ṣalaye pe iya onile naa, Arabinrin, Adejọke Salau, ẹni ọdun mejilelọgọta lo wa fi ẹjọ sun wi pe wọn dana sun ile oun.
 
O ni bi ina ọhun ṣe n jo, awọn araale ko raaye lati sa jade kuro ninu yara, ṣugbọn ti ori pada ko wọn yọ, nipa iranlọwọ awọn ara adugbo.
 
Oyeyẹmi sọ pe awọn araale lo tu aṣiri pe Hassan lo wa dana sun ile, idi ree ti wọn fi lọ gbe e nile ẹ. A tiẹ gbọ pe Hassan kọkọ purọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.
 
Ṣugbọn nigba to ya, to rii pe ko sibi toun fẹẹ ti ọrọ naa si, lo mu ko pada jẹwọ pe otitọ ni pe oun dana sun ile naa, ati pe yara ololufẹ oun tẹlẹ nikan loun fẹẹ dana sun, toun ko si mọ pe aṣiri maa pada tu sita.
 
Nigba to n sọ idi to fi ṣe bẹẹ, o ni awọn mejeeji jọ n fẹ ara awọn tẹlẹ ni, ṣugbọn lojiji lo ja oun ju silẹ, to si loun wa gbogbo ọna lati jẹ k'awọn fẹra, ṣugbọn ti ko gba.

O ni ibinu naa lo jẹ koun pada lọ sileẹ lati gbẹsan. Idi ree toun fi lọ ra pẹtiroolu ẹẹdẹgbẹta naira lati fi ṣiṣẹ buruku naa.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Frank Mna ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ ọdaran tẹsiwaju iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI