Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna niluu Akungba Akoko, ijọba Akoko South-West, l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii nigba ti wọno l'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun gun ọkan lara awọn akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu Akungba Akoko, ipinlẹ Ondo.
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fidi rẹ mulẹ pe ko si nnkan meji to da wahala silẹ, bi ko ṣe ti ọrọ owo, ẹgbẹrun kan naira to da ija silẹ laaarin Akintọla ati ẹnikan.
Wọn ni ki oloju to o ṣẹ ẹ, wọn ti gun Akintọla ni ọbẹ, to si ṣe bẹẹ ṣubu lulẹ gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe ẹni to gun Akintọla pa ti juba ehoro, ti ọwọ ọlọpaa ko si tii tẹ ẹ.
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmilayọ Ọdunlami-Omisanya nigba to n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ṣalaye pe ọsibitu ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe Akintọla ti ku, lẹyin ayẹwo.
O ni aawọ lo ṣẹlẹ laaarin oloogbe naa, ati ẹnikan, to fi di pe awọn mejeeji bẹrẹ sii tahun sira wọn, ti ọrọ naa si gba ibi ti ẹnikẹni ko lero lọ.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa lẹkunrẹrẹ, pẹlu ọrọ idaniloju pe ọwọ yoo tẹ ẹni to pa Akintọla.
AWIKONKO gbọ pe iṣẹlẹ yii mu ki gbogbo agbegbe ti wahala naa ti bẹ silẹ pa lọlọ, ti awọn eeyan si sa asala fun ẹmi wọn
Bakan naa la tun gbọ pe awọn kan lọ dana sun ile awọn eeyan ẹni to pa Akintọla, lati fi ẹhonu wọn han.
No comments:
Post a Comment