Ọdun mẹwaa ni mo fi duro lati pa ọrẹ mi to gba ọkọ lọwọ mi - Anita jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 7, 2023

Ọdun mẹwaa ni mo fi duro lati pa ọrẹ mi to gba ọkọ lọwọ mi - Anita jẹwọ


Anita Ofili, ẹni tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo tẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2023 lagbegbe Greenville Estate niluu Ajah, ipinlẹ Ekoo ti sọ idi pataki to fi pa ọrẹ rẹ danu.
 
Ọwọ ọlọpaa lo tẹ Anita lori ẹsun wi pe o gun ọrẹ rẹ, Glory Okon pa ni nnkan bi aago kan kọja ogun iṣẹju, ọjọ naa, to tun jẹ ọjọ Aiku, Sannde.
 
Anita sọ pe Glory gba ọkọ afẹsọna oun lọdun mẹwaa sẹyin, to si ni latigba naa loun ti n wa ọna boun yoo ṣe gbẹsan.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ariwo 'ẹ gba mi', lo mu k'awọn ara ile ti Glory n gbe fura, ti wọn fi yọju loju ferese, eyi jẹ kayeefi nigba ti wọn ri obinrin naa ninu agbara ẹjẹ.
 
Wọn ni ọmọ baba onile to jẹ obinrin lo lọ yọju loju ferese Glory, to si ri ẹnikan to fi aṣọ boju, eyi to jẹ ko sare lọ pe baba rẹ to ni ile lati ṣalaye ohun ti oju rẹ ri fun un.
 
Baba onile naa lo lọ pe awọn araale yooku, ti wọn si fipa ja ilẹkun wọle. Igba ti wọn ṣi aṣọ loju ẹni to boju naa, o jẹ iyalẹnu pe Anita, ọrẹ Glory ni.
 
Loju ẹsẹ ni wọn ti sare ranṣẹ s'awọn ọlọpaa lati wa wo ohun ti oju wọn ri. Ṣugbọn k'awọn ọlọpaa too debẹ, wọnn ti sare gbe Glory digbadigba lọ si ọsibitu lati doola ẹmi ẹ.
 
O ṣeni laanu pe ẹnu ọna ọsibitu naa ni Glory dakẹ si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI