O ma ṣe o! Olori Ogboni padanu ẹmi ẹ sinu ijamba ọkọ l'Ọṣun, awọn iyawo ẹ ti wọn jigbe lo n wa lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 6, 2023

O ma ṣe o! Olori Ogboni padanu ẹmi ẹ sinu ijamba ọkọ l'Ọṣun, awọn iyawo ẹ ti wọn jigbe lo n wa lọ


Iṣẹlẹ ti ko fi bẹẹ dun mọ awọn eeyan ninu lo ṣẹlẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, iyẹn nigba ti olori awọn Ogboni Agbaye, Ọba Adetoyeṣe Ọlakisas at'awọn meji kan padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ n'ipinlẹ Ọṣun.
 
Ọba Ọlakisan to tun jẹ Awiṣẹ Ilẹ Yoruba la gbọ pe o padanu ẹmi ẹ sinu ijamba ọkọ lakoko to n wa awọn iyawo ẹ meji t'awọn ajinigbe jigbe lọjọ Aiku, Sannde.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lawọn ajinigbe kan lo yawọ ile Oloogbe naa to wa niluu Imẹsi Ile, ti wọn si ji awọn iyawo ẹ meji ti wọn ba nile gbe salọ.
 
Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti lọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti, ti iwadii si bẹrẹ lati ri wọn gba pada.
 
AWIKONKO gbọ pe ibi Awiṣẹ ati awọn meji naa ti n wa ọna bi wọn yoo ṣe ri awọn iyawo ẹ mejeeji gba pada lo ti kagbako ijamba ọkọ, ti awọn mẹtẹẹta to wa ninu mọto naa si ku loju ẹsẹ.
 
Wọn lawọn meji naa ti wọn jọ ku sinu ijamba mọto jẹ ọlọpaa
 
Yẹmisi Ọpalọla, to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe igbesẹ ṣi n lọ lọwọ lati mọ ibi ti wọn gbe awọn obinrin meji naa lọ, lati le gba wọn jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI