Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ni ọrọ iku akẹkọọ fasiti tiluu Benin kan, iyẹn University of Benin (UNIBEN), to wa nipinlẹ Ẹdọ, Mayor ṣi n jẹ f'awọn eeyan ẹ, paapaa awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ.
Ọjọ Aje, Mọnde la gbọ pe awọn kan ti imura wọn jọ ti ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun yinbọn pa a danu, iyẹn ni nnkan bi aago mẹsan alẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to le sọ pato, boya oun naa wa lara awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun, ṣugbọn sibẹ, ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe 'ẹni ti ko ba jẹ gbi, ko le ku gbi.'
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ẹdọ ti jẹ ko di mimọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ lati mọ awọn to yinbọn Mayor, gẹgẹ bi awọn tiẹ ṣe maa n pe e.
Wọn ni Mayor gbajumọ daadaa ninu ọgba fasiti naa, ẹni ti wọn sọ pe ipele to kẹyin lo wa ni ẹka ikẹkọọ Public Administration lo wa, iyẹn ni ipele to kẹyin, eyi ti a mọ si Final Year.
Inu yara la gbọ pe wọn ti yinbọn pa a.
Bẹẹ la tun gbọ pe awọn ọlọpaa ni wọn pada gbe oku ẹ lọ si mọṣuari ọsibitu fasiti Uniben, iyẹn University of Benin Teaching Hospital (UBTH), nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe ẹlẹmi ti gba a.
No comments:
Post a Comment