Opin de ba gbogbo rogbodiyan: Macgregor gba ade Olu Orile-Ilawọ, ni Dapọ Abiọdun ba sọ pe ẹni ti ọba yẹ ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 25, 2023

Opin de ba gbogbo rogbodiyan: Macgregor gba ade Olu Orile-Ilawọ, ni Dapọ Abiọdun ba sọ pe ẹni ti ọba yẹ niGomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti sọ pe ẹni ti ipo Ọba tọ si l'awọn gbe ade, ọpa aṣẹ ati iwe ẹri fun gẹgẹ bi Olu tiluu Orile Ilawọ, to si ni bi wọn ṣe yan Ọba Oluṣẹgun Alexander Macgregor lo lọ ni ibamu pẹlu eto ifinijoye n'ipinlẹ naa.

Abiọdun lo sọ eyi lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee lasiko to n gbe ade ati ọpa aṣẹ fun Ọba Oluṣẹgun Alexander Macgregor gẹgẹ bi Olu Orile-Ilawọ.

Nigba to n gba ẹnu Gomina Dapọ Abiọdun sọrọ, Kọmiṣanna f'ọrọ eto oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, Ọnarebu Ganiu Hamzat ki awọn araalu naa ku oriire fun bi wọn ṣe dibo yan Macgregor gẹgẹ bi ọba wọn.

Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ...

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI