Sọdiq, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun to n digunjale l'Ọṣun ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 21, 2023

Sọdiq, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun to n digunjale l'Ọṣun ti ha o


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹtalelogun kan, Adeleke Sọdiq lori ẹsun idigunjale.
 
Gẹgẹ bi Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe ṣalaye, o ni  ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun pọmbele ni Sọdiq niluu Oṣogbo, ipinlẹ naa.
 
Ọpalọla sọ pe ẹgbẹ okunkun ti Sọdiq wa lo fi n dunkooko mọ awọn eeyan, ko to di pe o lọ digun ja ẹnikan to n jẹ Joseph Wusu lole lagbegbe Technical College niluu Oṣogbo
 
Siwaju sii lo sọ pe awọn ọlọpaa ẹka to n gbogun iwa ẹgbẹ okunkun, iyẹn Anti-Cultism Squad lo rọwọ to Sọdiq, lẹyin tawọn kan fi to wọn leti nipa iṣẹ buruku to ṣẹṣẹ ṣe.
 
Bakan naa lo sọ pe o pẹ t'awọn ti n gburo nipa b'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe n dunkooko mọ awọn araalu, ti wọn ko si f'awọn eeyan lọkan balẹ.
 
Koda, o ni niṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii yoo tun fi ipa mu awọn eeyan lati lọ gba owo ninu apo ile ifowopamọ si wọn, pẹlu nnkan ija oloro.
 
Ọpalọla sọ pe Sọdiq at'awọn eeyan rẹ lo tẹle Joseph loju ọna, ti wọn si ni ko ṣi foonu rẹ pẹlu nnkan ija oloro ti wọn ko dani. Nigba ti wọn yọ owo to wa ni banki rẹ wo, ni wọn sọ ep ko fi ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira [N150,000] ranṣẹ si wọn, ko ti di pe wọn salọ.
 
Joseph lo gba teṣan lọ lati fi to awọn ọlọpaa leti, ko ti di pe wọn ṣewadii.
 
Sọdiq nigba tọwọ tẹ ẹ, pada jẹwọ f'awọn ọlọpaa pe otitọ loun wa ninu ẹgbẹ okunkun.
 
Ọpalọla ti wa jẹ ko di mimọ pe ọwọ yoo tẹ awọn yooku lati fi wọn jofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI