A ko fi ofin de jijẹ Indomie, kii ṣe majele rara - Ọga agba NAFDAC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 5, 2023

A ko fi ofin de jijẹ Indomie, kii ṣe majele rara - Ọga agba NAFDAC


Latari iroyin kan to deede gba ori ayelujara kan, pe ohun jijẹ Indomie noodles ko dáa fara, ati pe eroja to n fa àisàn jẹjẹrẹ tá a mọ sí kansa wa ninu rẹ, Ọga agba nileeṣẹ to n ri sí ounjẹ ati òògùn lílò lorile ede yii, (NAFDAC), ìyẹn. Mojisola Adeyẹye ti ṣalaye pe irọ gbuu ni iroyin naa. 

O ni Naijiria nibi ni wọn ti n ṣe Indomie ta a n jẹ nile yii jade, ki í ṣe ilẹ òkèèrè bi iroyin ofege naa ti wí, bẹẹ ni Indomie ki í fa jẹjẹrẹ. Nitori naa, o ni k'awọn eeyan máa ra Indomie ti wọn n ṣe nilẹ yii kì won sì máa jẹ e lọ bi ìṣe wọn, ki í ṣe majele rara, awọn ko sí fòfin de jijẹ rẹ.

Atejade kan to ti ọdọ ajọ NAFDAC wa lo fidi e múlẹ, pe ọpọlọpọ èèyàn ni Naijiria lo máa n kaya soke bi wọn bá ti gbọ pé nnkan jíje to da bíi Indomie n fa wahala sí àgọ ara, wọn yoo ti ro pe Indomie gangan ni. 

Bẹẹ, ọpọlọpọ ounjẹ to da bíi Indomie lo wa to n ti awọn ileeṣẹ mi-in wa, ti wọn lórúko tiwon lọtọ, sibe,awọn èèyàn yóò máa ro pe Indomie gangan ni, wọn yóò sì ṣe bẹẹ máa sọ ounjẹ naa loruko ti ko jẹ, wọn yóò máa bẹrù lati ra a loja gbogbo.

Wọn ní k'awọn ọmọ Naijiria lọọ mọ pe orilẹ ede yii ni won ti n ṣe Indomie, ẹyà ti wọn sì sọ pe o ni eroja 'ethylene oxide' to n fa jẹjẹrẹ ko sí ní Naijiria yii rara, bẹẹ ni wọn kò sí kí n ko o wá síbi lati oke okun.

Lati tubo tan imọlẹ sí iroyin to gbòde kan naa, ajọ yii ṣakawe ohun to ṣẹlẹ ní Egypt lodun 2022, nigba ti iroyin kan jade to n kilọ pe k'awọn eeyan ma jẹ awọn eya 'noodles' kan, nitori won ni ohun to lè ṣe ara nijamba wa ninu rẹ. 

Niṣe niroyin naa tan kale de awọn orilẹ ede mi-in to mule ti Egypt, to dohun t'awọn eeyan n bẹrù kiri.

Gege bi wọn ṣe wí, awọn iroyin to le ko ni laya soke bii ti ilẹ Egypt igba náà ló tún gbòde kan lorilẹ ede yii, ìyẹn ló sì fa a ti àjọ National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC) ati Standards Organization of Nigeria (SON), ṣe fìdí rẹ múlẹ, pe ohun jijẹ ti wọn lo n ṣọ̀ṣẹ naa ko dé Naijiria lati ipasẹ awọn onifayawọ. 

Nigbeyin, kedere lo foju hàn pé ounjẹ naa ko dé enuubode Naijiria, débi tí yoo tilẹ wọ ọjà tiwa rara.

"Lọwọ yii naa ti wọn ṣawari eroja ethylene oxide to n fa kansa ninu eya Indomie’“special chicken” ni Taiwan ati Malasia, ibẹrubojo tun ti gbalẹ̀ kan ni Naijiria.

Awọn oniroyin kan náà ti bẹrẹ sí i gbé àkòrí iroyin to le mu ipayinkeke jade, wọn sì n jẹ k'awọn eeyan maa ro nnkan mi-in lori ohun jijẹ Indomie. 

"Ileeṣẹ Indofood lo n ṣe Indomie ni Taiwan ati Malaysia, ṣugbọn o jẹ ijọniloju pe ileeṣẹ Dufil Prima Food Plc to n ṣe Indomie ni Naijiria lo n foriko iwadii to le nitori ohun ti ko kan won to n ṣẹlẹ lẹyìn odi.

"Awọn akori alariwo to n t'ọdọ awọn oniroyin kan wa lo n jẹ k'awọn eeyan máa ro pe bi won ṣe pàṣẹ pé k'awọn 'noodles' kan ma wọ Naijiria ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ní, ṣugbọn ootọ to wa nibe ni pe odun gbọọrọ sẹyìn ni wọn ti fi ote le e pe awon ounje bi noodles ko gbọdọ wọlé sí Naijiria lat'oke okun mọ, k'awọn ileeṣẹ ile yìí lè goke agba, ki wọn sì lè máa tẹsiwaju" Bẹẹ ni atejade naa wi, 

Nigba to n ba awọn akọroyin soro lori ọrọ Indomie yii, Ọga agba NAFDAC, Mojisọla Adeyẹye, ṣalaye pe okan lara awon ounje tijoba fòfin de pe won ko gbọdọ wọ Naijiria ni awon ounje bíi noodles yii, o sí ti wa bẹẹ tipẹ. 

Eyi ti wọn tile n sọ pé o ni eroja buruku ninu yii paapaa ko sí nínú ìwé àkọsílẹ ajọ NAFDAC gẹgẹ bo ṣe wi, wọn o sì ki n ṣe e ni Naijiria yii rara ni.

Ọga agba NAFDAC naa sọ pe, "A ti bẹrẹ ìwádìí lori awọn ohun jijẹ Indomie ati nnkan amounje dun ti wọn fi n ṣe e (Seasoning), bẹẹ la si n wadii lati mọ boya ayederu noodle yii gba ona awọn onifayawọ wole si orilẹ ede yii. To ba sì wole síbi, awọn ikọ to n ri sí ifinmu-filẹ yoo ṣawari rẹ jáde.

"A tún fẹẹ ri i daju pe a ṣayẹwo awọn eroja ti wọn n lo fún Indomie atawọn ounjẹ bíi rẹ yooku. Ajọ NAFDAC ko fofin de Indomie" Bẹẹ ni ọga agba NAFDAC wí.

Bakan naa ni Alabojuto to n ri sí ikede nileeṣẹ Dufil Prima Foods Plc, Tope Ashiwaju, kín ọrọ yìí lẹyin pẹlu alaye pe,

“A fẹẹ fi da gbogbo awọn oníbàárà wa pataki ni Naijiria loju pe gbogbo Indomie ti won n ra nile yii ko ti oke òkun wa, orilẹ ede Naijiria nibi ni wọn ti n ṣe e labẹ ilana to tele ofin ìpèsè ohun jijẹ lagbaaye, ilana ISO ti wọn fonte lu la ṣì n lọ.

" Ko sí Indomie tẹ e ra ti a ko fi ilana NAFDAC gbe jade, gbogbo ofin wọn là n tẹle, bẹẹ náà la n tẹle ofin Standards Organization of Nigeria (SON). 

"Awọn eroja to dára jù la n lọ, awọn oniṣowo to ṣeé f'ọkan tan la n ra eelo lọdọ wọn, awọn ibi tá a si ti n ṣiṣẹ ree, gbogbo igba ni wọn waa n yẹ e wo láti rí ì pe bo ṣe yẹ k'ohun gbogbo ri lo n ri nigba gbogbo. A kì í fi ojúṣe wa silẹ láì ṣe nileeṣẹ tiwa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI