O pari! Wọn ti ju Ekweremadu ati iyawo ẹ sẹwọn ọdun mẹsan-an oooo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 5, 2023

O pari! Wọn ti ju Ekweremadu ati iyawo ẹ sẹwọn ọdun mẹsan-an oooo


Ile ẹjọ ilẹ Amẹrika ti ju Aarẹ ile igbimọ aṣofin orileede Naijiria tẹlẹ, Ike Ekweremadu, iyawo ẹ, Arabinrin Beatrice ati dokita wọn, Obinna Obeta sẹwọn lori ẹsun buruku to nii ṣe pẹlu tita ẹya ara eeyan lọna aitọ ti wọn fi kan wọn.
 
Ẹwọn ọdun mẹsan ati oṣu mẹjọ ni wọn ju Ekweremadu,nigba ti wọn ju iyawo ẹ, Beatrice sẹwọn ọdun mẹrin ati oṣu mẹfa gbako.
 
Yatọ si awọn meji yii, wọn tun ju dọkita wọn, Obeta sẹwọn ọdun mẹwaa gbako.
 
Inu oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii ni aridaju fi han nile ẹjọ naa to wa ni Old Bailey pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta.
 
Nibẹ ni wọn ti tu ọmọ wọn, Sonia silẹ wi pe ko mọ nnkankan nipa ẹsun naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI