Adeyẹmi to ja ibale ọmọ rẹ, ọmọ ọdun marun-un l'Ogun yoo foju ba ile-ẹjọ - Ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 27, 2023

Adeyẹmi to ja ibale ọmọ rẹ, ọmọ ọdun marun-un l'Ogun yoo foju ba ile-ẹjọ - Ọlọpaa


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe baale ile, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Adeyẹmi Babatunde to ja ibale ọmọ rẹ, ọmọ ọdun marun-un lagbegbe Ijẹbu-muṣhin yoo foju ba ile-ẹjọ, lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lẹkunrẹrẹ.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọlanrewaju Ọladimeji lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ wọn, Abimbọla Oyeyẹmi fi sita laipẹ yii.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni iya ọmọ naa, to tun jẹ iyawo Adeyẹmi lo gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti pe ọkọ oun fipa ja ibale ọmọ ọdun marun-un toun bi fun-un.
 
Obinrin naa sọ pe gbogbo igba toun ba n wẹ fun ọmọ naa, toun ba si ti mu ọwọ de ibi abẹ rẹ lati fọ ọ lo maa n pariwo pe abẹ naa n dun oun, ati pe igbakugba too ba fẹẹ tọ lo maa sunkun wi pe abẹ n dun oun gidi gan-an.
 
Iyaale ile yii wa fi kun ọrọ rẹ wi pe oun nilo lati farabalẹ bi ọmọ naa leere nipa ohun to ṣẹlẹ sii gangan, ko to di pe o pada jẹwọ wi pe baba oun lo ba oun laṣepọ lori bẹẹdi nigba tawọn ba ti jọ wa papọ.
 
Loju ẹsẹ ni obinrin naa ti gba teṣan ọlọpaa lọ, to si pariwo sita wi pe k'awọn araalu gba oun lọwọ ọdaju baba ati ọkọ toun fẹ.
 
Awọn ọlọpaa ẹkun Ijẹbu Muṣhin ko fi ọrọ ọhun falẹ rara, ti wọn fi lọ gbe Adeyẹmi nibi to wa, ti wọn si loun naa jẹwọ pe otitọ ni, ati pe oun kii mọ igba toun ba n ṣiṣẹ buruku naa, o digba toun ba ṣetan ki oju oun too ṣẹṣẹ la.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI