Fẹmi to fi iwakuwa tirela pa eeyan mẹrin danu l'Oṣogbo foju ba ile-ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 27, 2023

Fẹmi to fi iwakuwa tirela pa eeyan mẹrin danu l'Oṣogbo foju ba ile-ẹjọ


Ika abamọ ni Baale ile, ẹni ọdun mẹtalelogoji kan, Fẹmi Ajayi fi sẹnu nile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Oṣogbo, nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun wọ ọ lọ sibẹ.
 
Ẹsun mẹsan ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu iwakuwa, aini iwe irinna, aini iwe ọkọ to pe at'awọn miran la gbọ pe wọn fi kan Fẹmi l'Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun yii ni Fẹmi fi mọto pa eeyan mẹrin danu, ni nnkan bi aago mẹsan aabọ aarọ ọjọ naa.
 
Agbegbe ti wọno pe ni Apoti to wa loju ọna Ile-Oluji, Ipetu-Ijẹṣa, ipinlẹ Ọṣun ni ijamba ọhun ti waye.
 
Agbefọba Akintunde Jacob, to wọ Fẹmi lọ sile ẹjọ naa ṣalaye pe tirela Howo Sino to ni nọmba idanimọ AKD 380 YE, ni ọkunrin naa fi ṣeku pa Kayọde Ọladunjọkẹ, Abudu Mariam, Ikuelọgbọn Tọmiwa ati Titilayọ Adedapọ.

Nibi ijamba naa la tun gbọ pe eeyan mẹta ọtọọtọ ti farapa yannayanna, ti wọn si ti ko wọn lọ si ọsibitu ti wọn ti n gba itọju.

Bakan naa ni Akintunde tun sọ pe Fẹmi ba mọto jiipu Lexus kan to jẹ ti Ọgbẹni Agboọla Ọpẹyẹmi jẹ.

O wa fidi rẹ mulẹ pe awọn ẹsun toun ka si Fẹmi lẹsẹ yii lo tako iwe ofin irinna labala 35, 142, 139, 7, 21 (b), 18, 27, Vol. 6 Cap 146 ati 147 ofin ipinlẹ Ọṣun, tọdun 2002, ati iwe ofin ọdaran labala 18 (1)  vol. VI , Cap 115 tipinlẹ naa, lọdun 2002.

Agbẹjọro ọdaran, K. Adepọju, nigba toun naa n sọrọ rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ lati gba beeli onibara rẹ, ko le maa gba ile wa jẹjọ.
 
Onidajọ A. Ọdẹlẹyẹ, wa gba ẹbẹ naa, to si ni ki wọn gba beeli Fẹmi pẹlu idaji miliọnu naira ati oniduro meji ọtọọtọ.

Nigba to n sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹta, oṣu keje, Onidajọ naa sọ pe awọn oniduro yii gbọdọ maa gbe ni ayika ile ẹjọ, bẹẹ ni wọn si gbọdọ jẹ awọn to n san owo ori wọno deedee, koda wọn gbọdọ fi fọto pelebe ati iwe ẹri Affidavit silẹ pẹlu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI