Aye o! Wọn ju gbajumọ ọba alaye sẹwọn ọdun mẹwaa l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 13, 2023

Aye o! Wọn ju gbajumọ ọba alaye sẹwọn ọdun mẹwaa l'Ondo


Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo ti ju Ọba Sunday Bọboye, Ajagun tiluu Ode to wa nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ sẹwọn ọdun mẹwaa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Kayeefi ni idajọ ọhun ṣi n jẹ fun awọn araalu, paapaa awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, pẹlu bi ile-ẹjọ ṣe sọ pe Ọba Bọboye jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni niṣe ni Ọba Bọboye lọ ba awọon nnkan ire oko oloko bii igi ọpẹ, igi ẹyin ati bẹẹbẹẹlọ jẹ, lai bikita.
 
Ẹsun mẹfa ọtọọtọ la gbọ pe wọn fi kan ọba naa niwaju Onidajọ Bukọla Ojo.
 
Nigba to n fẹsun kan ọba naa niwaju ile ẹjọ, Agbefọba Ajiboye Babatunde, ṣalaye pe nnkan bi aago mẹta ọsan, ogunjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 2022 ni “Pastorate and Laity of the Apostolic Church Nigeria, to wa loju ọna Ado Ekiti, Igoba.
 
Wọn ni niṣe ni ọba naa ta ilẹ ti ire oko oloko wa lori ẹ fun ijọ naa. Ati pe pasitọ ijọ naa, ati gbogbo awọn ti wọn jọ lọwọ si iwa buruku naa ti na papa bora.
 
A gbọ pe owo ti wọn fi ṣe ọgba ilẹ naa ko din ni miliọnu kan naira, bẹẹ ni awọn nnkan ire oko ori ilẹ naa ko din ni miliọnu marun-un naira.
 
Babatunde fi kun ọrọ rẹ pe kabiyesi yii ko le ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa idi to fi gbe igbesẹ naa, nigba tọwọ tẹ ẹ, eyi lo jẹ ki wọn foju rẹ ba ileẹjọ.
 
Ẹsun to lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 516, 451, 249(d), ati 81, Cap. 7 vol. 1, tipinlẹ Ondo lọdun 2006.
 
Onidajọ Ojo wa paṣẹ pe bi Bọboye ba le san miliọnu marun-un naira gẹgẹ bi owo gba mabinu fun awọn nnkan to bajẹ, ko gbagbe nipa ẹwọn ti ile ẹjọ ju sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI