Dapọ Abiọdun tu igbimọ iṣakoso rẹ ka l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 26, 2023

Dapọ Abiọdun tu igbimọ iṣakoso rẹ ka l'Ogun


Ni bi ọjọ meloo kan ki iṣakoso saa akọkọ rẹ kogba wọle, Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti tu igbimọ iṣakoso rẹ ka, to si ti ki gbogbo awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ fun aduroti wọn.

Oni, tii ṣe Ọjọ Ẹti, Furaidee ni Gomina Dapọ Abiọdun kede wi pe oun ti tu igbimọ iṣakoso oun ka, lati le tun awọn igbimọ iṣakoso miran yan fun saa keji rẹ, ti yoo bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ.
 
Lakoko to n kede sita, o dupẹ lọwọ gbogbo igbimọ iṣakoso naa ti a mọ si State Executive Council fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lori aṣeyọri saa akọkọ rẹ to fẹẹ kogba wọle, eyi to pe ni "Building our Future Together Agenda".

Eto ọhun la gbọ pe o waye ninu gbọngan awọn alakoso to wa ninu ọfiisi gomina, iyẹn Exco Chamber Governor's Office, Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.
 
Nibẹ lo si ti fi idunnu rẹ han wi pe awọn alabaṣiṣẹpọ oun naa ti ṣiṣẹ takuntakun lati sin ipinlẹ Ogun ni bi agbara wọn ṣe ka, paapaa nipa ifọwọsowọpọ.

"Gbogbo yin lẹ ti ṣiṣẹ papọ, ti ẹ si ti ṣe daadaa lati sin awọn araalu nipa agbekalẹ eto 'kikọ ọjọ iwaju wa papọ', eyi to jẹyọ lara ohun idanimọ wa ti a mọ si IṢẸYA

"A sare ije to dara. A si mu ayipada rere ba awọn eeyan wa. Gbogbo yin lẹ ni ibi ti a pin-in yin si, mo si fẹẹ dupẹ gidigidi lọwọ yin fun ipa ti ẹ ko. Ẹ ti wa di mọlẹbi mi bayii. Ẹ ma ṣe gbagbe ara yin nitori pe awọn eeyan yin ṣi maa pe yin lati ṣiṣẹ nibi to yẹ.

"Gbogbo wa la jọ bẹrẹ papọ, a si tun jọ wa nibi papọ, Ọlọrun ti gbe awọn kan gunke, bẹẹ la ko si padanu ẹnikẹni. Ni ibamu pẹlu ofin, ati pẹlu ibanujẹ, mo kede ituka igbimọ alabaṣiṣẹpọ mi lonii, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023."
 
Nigba to n gba ẹnu awọn ọmọ igbimọ naa sọrọ, igbakeji gomina, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele dupẹ gidigidi lọwọ gbogbo awọn to ti fi ara wọn jin fun iṣẹ isinlu, bẹẹ lo dupẹ lọwọ gomina fun anfaani to fun wọn lati ṣiṣẹ sin ipinlẹ wọn.

Olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Kọlawọle Fagbohun nigba toun naa n sọrọ sọ pe gomina ti mu ireti wa f'awọn alainireti, paapaa julọ lẹka igbanisiṣẹ ati igbega lẹnu iṣẹ ijọba.
 
O ṣalaye siwaju pe gomina mu ileri rẹ ṣẹ nipa sisan  owo ifẹyinti, bẹẹ lo ṣeleri wi pe awọn yoo tubọ gbauruku tii ninu iṣakoso saa rẹ keji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI