Ọwọ tẹ gendekunrin marundinlaadọta lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 26, 2023

Ọwọ tẹ gendekunrin marundinlaadọta lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'ipinlẹ Ogun


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tiluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin marundinlaadọta lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo'.
 
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii ni ajọ EFCC sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn eeyan naa niluu Ijẹbu, ipinlẹ Ogun, lẹyin olobo ti wọn lo ta si wọon leti.
 
Lara awọn tọwọ tẹ ni; Ogundiya Alex Oluṣẹgun, Ogunnusi Oluwaṣeunfunmi Akorede, Idor Ndubuisi Samuel, Bakare Idowu Ayọmide, Ọduntan Durojaiye Oluwaṣeun, Nurudeen Ọlalekan Quam, Bakare Taiwo Adewale ati Aiyeloja Ridwan Oluwatobi.

Awọn miran ni; Owolabi Imọlẹayọ Sọdiq, Samọd Tijani Owolabi, Abulele Joshua Osas, Agbọlade Mayọwa Oluwafẹmi, Oluṣọga Ridwan Oluwatobi, Fetuga Ọlajide Abiọdun, Agbọlade Bukọla, Odude Ayọmide Micheal, Adesanya Ọlamilekan, Badaru Damilare Micheal ati Bashir Sọdiq Ọmọbọlaji.
 
Ninu atẹjade ti ajọ naa gbe sita lọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn gba mọto bọginni mẹrindinlogun, foonu olowo iyebiye to pọ, oriṣiriṣi kọmputa alegbeka, aago ọwọ ati awọn nnkan miran.

Bakan naa ni wọn fi kun ọrọ wọn wi pe awọn yoo foju wọn ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lori wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI