Ẹ woju awọn mẹta ti wọn ti ba awọn ọmọ keekeeke laṣepọ l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 2, 2023

Ẹ woju awọn mẹta ti wọn ti ba awọn ọmọ keekeeke laṣepọ l'Ekoo


Ijọba ipinlẹ Ekoo labẹ Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gbe orukọ awọn mẹta kan ti wọn fẹran lati maa fipa ba awọn ọmọ keekeeke laṣepọ karakara nipinlẹ naa, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi.
 
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni ijọba Ekoo gbe oju awọn eeyan naa s'oju opo Twitter wọn, lati jẹ k'awọn eeyan kaakiri agbaye mọ iru eeyan ti wọn jẹ.
 
Ikanni Domestic and Sexual Violence Agency, @Lagosdsva ni wọn gbe e si.
 
Ninu ọrọ ti ajọ naa fi ti fọto ọhun nidii, wọn jẹ ko di mimọ pe idajọ ododo ti waye lori awọn mẹtẹẹta, ti wọn si ti wa lọgba ẹwọn, nibi ti wọn ti n jiya ẹṣẹ wọn.
 
Ọkan lara wọn, Idowu Daniel ni wọn ju sẹwọn ọdun meje gbako, nigba ti wọn ju Moses Ọlawale sẹwọn ọdun mẹtadinlogoji, eyi ti ẹnikẹta, Akin Isaac si gba idajọ ẹwọn ọdun mọkanlelogun pẹlu iṣẹ aṣekara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI