Fatai atawọn ọrẹ rẹ ti wọn yan iṣẹ adigunjale laayo ha l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 1, 2023

Fatai atawọn ọrẹ rẹ ti wọn yan iṣẹ adigunjale laayo ha l'Ogun


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹrin kan ti wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ adigunjale lọ, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe ẹkunrẹrẹ iwadii ti bẹrẹ lori wọn.
 
Agbegbe Sango Ọta, ipinlẹ Ogun lọwọ palaba wọn ti segi, ti a si gbọ pe agbegbe yii lawọn mẹrẹẹrin ti n ṣọṣẹ buruku wọn, ko to di pe ọwọ tẹ wọn.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi ṣe ṣalaye, o ni Ṣẹrif Kamọru, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Rabiu Seyidu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji; Ọpẹyẹmi Adebayọ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati Ajibọla Fakọlade toun jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun lawọn tọwọ tẹ.
 
Oyeyẹmi sọ pe ogunjọ, oṣu kẹta, ọdun 2023 ni ẹnikan to n jẹ Adelẹyẹ Sunday lọ fi to awọn ọlọpaa leti wi pe awọn tọọgi kọlu oun ni nnkan bi aago marun-un aabọ lagbegbe Jọju.
 
Siwaju sii lo sọ pe wọn gba foonu lọwọ oun, bẹẹ ni wọn tun fi ada ṣa oun l'ọrun, ti wọnn si tun yọ owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira ninu apo ile ifowopamọsi oun, ko to di pe wọn na papa bora.
 
Eyi lo mu ki ọga ọlọpaa ẹkun Sango Ọta, CSP Saleh Dahiru dide, to si bẹrẹ iwadii, koda, niṣe lo yan awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ lati ṣewadii.
 
Ko pẹ rara ti ọwọ fi tẹ awọn mẹrin ninu wọn nibi ti wọn fi ṣe ibugbe.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni ada, foonu Tẹkino POP2 to jẹ ti ẹni ti wọn jagba, awọn aṣọ iboju at'awọn nnkan miran.
 
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Ọlanrewaju Yọmi Ọladimeji ti wa paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju, ko to di pe wọn foju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI