Mi o ni tori aṣiṣe kan ṣoṣo ta De Gea danu - Ten Hag sọrọ lẹyin ti Man U padanu sọwọ West Ham - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 8, 2023

Mi o ni tori aṣiṣe kan ṣoṣo ta De Gea danu - Ten Hag sọrọ lẹyin ti Man U padanu sọwọ West Ham


Akọnimọngba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United, Erik Ten Hag ti sọ pe oun ko ni erongba kankan lati ta aṣọle, iyẹn Goalkeeper wọn, David De Gea danu lori aṣiṣe to ṣe, eyi to jẹ ki wọn padanu ifẹsẹwọnsẹ to waye laaarin awọn ati ikọ ẹgbẹ agbabọọlu West Ham.

Ten Hag sọ pe lotitọ ni De Gea ṣe aṣiṣe nla, eyi to jẹ ki wọn padanu sọwọ ẹgbẹ agbabọọlu West Ham ti wọn lọ ba nile lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ana.

Aami ayo kan si odo ni West Ham fi bori ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni papa iṣere ti London.

Ten Hag sọ pe aṣiṣe nla ni De Gea ṣe nigba ti agbabọọlu ọwọ iwaju fun West Ham, iyẹn Said Benrahma gba bọọlu sile laaarin iṣẹju mẹtadinlọgbọn ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Bi Manchester United ṣe padanu ti jẹ ki wọn ja wa silẹ lori tabili idije Premier League lati ipo kẹta si ipo kẹrin.

Ẹgbẹ agbabọọlu Newcastle lo wa ni ipo kẹrin tẹlẹ, ṣugbọn ni bayii, wọn ti rapala wọ ipo kẹta, ti wọn si n fi aami ayo meji ṣiwaju Man U.

Igba kẹrin ree ti a gbọ pe De Gea yoo maa ṣe iru aṣiṣe bayii, to si n mu ki wọn padanu sọwọ alatako wọn.

Ten Hag ti wa jẹ ko di mimọ pe oun ṣi fẹ ki De Gea duro ninu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ni saa yii, ati awọn saa to jmn bọ lọjọ iwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI