Awọn to n gbe ayederu iroyin nipa wa ko ṣe iwadii kikun - Adron Homes - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 7, 2023

Awọn to n gbe ayederu iroyin nipa wa ko ṣe iwadii kikun - Adron Homes


Awọn alakoso ileeṣẹ Adron Homes and Properties Ltd lorileede Naijiria ati kaakiri agbaye ti jẹ ko di mimọ pe iroyin kan to n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara kii ṣe otitọ rara, bi ko ṣe irọ to jinna si otitọ pọmbele.
 
Laipẹ yii ni iroyin kan jade sori ikanni ayelujara, nibi ti wọn ti fẹsun kan ileeṣẹ Adron Homes to n ta ilẹ ati ile, paapaa dukia kaakiri orileede Naijiria wi pe wọn kii f'awọn eeyan ni ilẹ, bi wọn ba ti san owo, ati pe wọn ko ni awọn lanlọọdu to n gbe ninu ọgba ti wọn ti n ta ilẹ, iyẹn Estates.
 
Ileeṣẹ Adron Homes, nigba ti wọn n ṣalaye jẹ ko di mimọ pe irọ to jinna si otitọ ni iroyin naa, nitori pe awọn lanlọọdu to le ni ẹgbẹrun meji lo n gbe ninu awọn ọgba wọn kaakiri Naijiria, ti wọn si n jẹri nipa awọn ohun amayedẹrun.
 
Wọn jẹ ko di mimọ pe awọn to n gbe ayederu iroyin nipa ileeṣẹ wọn ko ṣe iwadii finnifinni, bẹẹ ni wọn ko wa si ileeṣẹ wọn lati beere  nipa ohun ti wọn ba fẹẹ mọ.
 
Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn n ṣe awọn nnkan to n tẹ gbogbo awọn onibara awọn lọrun, ati pe gbogbo eto, ofin ati ilana ijọba lawọn n tẹle ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI