Ohun ti mo fẹ ki ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ṣe ti a ba pade ni papa iṣere Emirates - Arteta sọrọ o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 1, 2023

Ohun ti mo fẹ ki ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ṣe ti a ba pade ni papa iṣere Emirates - Arteta sọrọ o


Akọnimọ-ọn-gba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Mikel Arteta, ti tu aṣiri ohun to fẹ ki ẹgbẹ agbabọọlu alatako wọn, iyẹn Chelsea ṣe bi wọn ba pade lati figagbaga ni papa iṣere Emirates nibi ifẹsẹwọnsẹ Premier League ti yoo waye lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọla.
 
Gbajugbaja Arteta sọ pe oun fẹ ki Chelsea wa gba gbogbo ohun ti wọn ba mọ lati gba, lati le lu wọn nibi ifẹsẹwọnsẹ naa.
 
Arteta lo sọrọ yii nibi ipade oniroyin to ṣe ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ to fẹẹ waye naa, eyi to pe lonii, ọjọ Ajẹ, Mọnde.
 
Ọkunrin naa loun mọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea dara pupọ, ko si si ọna ti wọn ko le fi gba bọọlu pẹlu oriṣiriṣi agbabọọlu.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, “Awọn [Chelsea] maa gbiyanju lati wa si Emirates lati wa lu wa.
 
“Wọn ni akọnimọ-ọn-gba to dara, agbabọọlu to da yatọ, ẹni ti eeyan ko le sọ ohun to le ṣe, nitori pe ko si ọna ti wọn ko le fi gba bọọlu pẹlu awọn agbọọlu loriṣiriṣi, ṣugbọn sibẹ, a maa gbaradi fun idijẹ naa ati bori.”
 
Aago mẹjọ alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee tii ṣe ọla ni ifẹsẹwọnṣe ọhun yoo bẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI