Ọmọbinrin arẹwa to n f'iṣẹ ọlọpaa lu jibiti l'Ọṣun ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Ọmọbinrin arẹwa to n f'iṣẹ ọlọpaa lu jibiti l'Ọṣun ti ha o


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan ti ko niṣẹ meji ju ko maa f'iṣẹ ọlọpaa lu awọn eeyan ni jibiti kaakiri igboro ilu Oṣogbo lọ.
 
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Yẹmisi Ọpalọla fi to awọn akọroyin leti, to si ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni ọwọ ni ọwọ tẹ ọmọbinrin naa.
 
Nigba to n sọrọ, o ni ẹnikan to n fi owo dokoowo, iyẹn POS Operator ni ọmọbinrin naa lọ lu ni jibiti obitibiti owo niluu Oṣogbo, ko to di pe ọwọ palaba rẹ segi.

O tẹsiwaju pe bi aṣiri rẹ ṣe tu, lawọn eeyan ti bẹrẹ sii luu, to si ku diẹ ki wọn pa a danu, ko to di pe awọn ọlọpaa ẹkun Ata-Ọja ti wọn ranṣẹ pe sare debẹ lati doola ẹmi rẹ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ṣe ni ọmọbinrin naa lọ ba ẹni to n fowo dokoowo yii, to si sọ pe ọlọpaa loun, ati pe teṣan Ata-Ọja loun ti n ṣiṣẹ.
 
O niṣe lo mu ọmọbinrin to n ṣiṣẹ nibẹ, to si gba baagi ọwọ rẹ to jẹ owo, ẹgbẹrun lọna ogun naira lo wa nibẹ, to si tun gba foonu rẹ ti owo rẹ to ẹgbẹrun mẹẹdogun naira lọwọ ẹ.
 
Bakan naa lo tun sọ pe ko lọ ṣe ẹda iwe kan wa, eyi to mu ko na papa bora, ki aṣiri rẹ ma ba a tu sita.
 
Nigba tọwọ pada tẹ ẹ, wọn ba owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna igba naira ataabọ, N246,650; ẹrọ igbowo, iyẹn Opay PoS machine ti owo rẹ ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira; kaadi idanimọ ti fasiti ipinlẹ Ekiti ati kaadi idibo alalopẹ kan lọwọ ẹ.
 
Siwaju sii ni iwadii awọn ọlọpaa tun fi han pe ọmọbinrin yii ti ji ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira yọ ninu ẹrọ PoS to jigbe, ti a si gbọ pe iwadii ọlọpaa ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lori ẹ.
 
Ọpalọla ti wa jẹ ko di mimọ pe ọmọbinrin naa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI