Ọwọ Amọtẹkun tẹ ọdaran meji to n ṣebi alaaganna l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Ọwọ Amọtẹkun tẹ ọdaran meji to n ṣebi alaaganna l'Ondo


Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka t'ipinlẹ Ondo ti gba awọn araalu lamọran lati maa ṣọra f'awọn to n ṣe bii alaaganna lagbegbe wọn, nitori pe ọpọ ninu wọn lo je ayederu.
 
Ọga agba Amọtẹkun nipinlẹ naa, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ nigba to n sọrọ l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii lakoko to n foju awọn ọdaran mẹrindinlọgbọn tọwọ tẹ han jẹ ko di mimọ pe awọn meji lọwọ tẹ, ti wọn n ṣebei alaaganna kaakiri igboro, to si jẹ pe iṣẹ ibi ni wọn n ṣe kaakiri.
 
Operatives of the Ondo State Security Network Agency, Amotekun Adelẹyẹ sọ pe nigba tọwọ tẹ ọkan lara awọn meji naa, wọn ba foonu olowo iyebiye lọwọ ẹ.
Ati pe ẹnikeji tọwọ tẹ lo ṣa baba onile rẹ pa, to si jẹ pe latigba naa lo ti n ṣebi alaaganna, ki ọwọ ma ba a tẹ ẹ.

Nigba to n sọrọ, o sọ pe ọpọ ninu awọn to n ṣebi alaaganna kaakiri igboro ni wọn jẹ ayederu lati maa fi ṣiṣẹ ibi, ṣugbọn to ni ọwọ ti pada tẹ meji ninu wọn, ti iwadii si ti n lọ lọwọ.
 

O ni agbegbe Idanre lọwọ ti tẹ ọkan lara wọn, nigba ti ọwọ tẹ ẹnikeji lagbegbe Igbara-Oke.
 
Nibẹ naa lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn mẹrinlelogun yooku tọwọ tẹ ni wọn ni oriṣiriṣi ẹsun bii idigunjale, ifipabanilopọ, ijinigbe ati awọn ẹsun miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI