Ọwọ Amọtẹkun tẹ Mustapha ati Ṣọla ti wọn fọ ile onile n'Ila-Ọrangun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 26, 2023

Ọwọ Amọtẹkun tẹ Mustapha ati Ṣọla ti wọn fọ ile onile n'Ila-Ọrangun


Ileeṣẹ eto aabo Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọrẹ meji kan,
Mustapha Fatia, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Adeniyi Ṣọla, toun jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn lori ẹsun ole jija ati fifọ ile onile.
 
Ọga agba fun ileeṣẹ aabo naa, Ajagunfẹyinti Bashir Adewinmbi lo fidi iroyin naa mulẹ, to si jẹ ko di mimọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja lọwọ tẹ awọn mejeeji naa.

Adewinmbi sọ pe awọn kan lo wa ta awọn oṣiṣẹ wọn leti ni ẹkun Ila, to si loju ẹsẹ ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, ko to di pe ọwọ pada tẹ wọn nibi ti wọn fi ṣe buba.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe agbegbe ọtọọtọ lọwọ ti tẹ awọn mejeeji, lori ẹsun wi pe wọn tun ji ọkada TVS ati awọn irin kan gbe, ti wọn si lọ lu gbogbo rẹ ni gbanjo.

Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe wọn tun ji awọn nnkan mimu ẹlẹrindodo gbe ninu ṣọọbu yii, ti wọn si ta gbogbo rẹ danu lowo pọọku.
 
O wa jẹ ko di mimọ pe awọn ti lọ fa awọn mejeeji le awọn ọlọpaa lọwọ fun itẹsiwaju iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI