Usman ji Bibeli gbe l'Abuja, l'Adajọ ba juu sẹwọn oṣu meji gbako - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 26, 2023

Usman ji Bibeli gbe l'Abuja, l'Adajọ ba juu sẹwọn oṣu meji gbako


Ẹwọn ikilọ ati ifanileti ni ile ẹjọ Grade I Area to wa lagbegbe Kabusa, niluu Abuja ju gendekunrin, ẹni ọgbọn ọdun kan, Zakaraya Usman si lori ẹsun wi pe o ji Bibeli gbe.
 
Usman ti wọn lo yan iṣẹ awọn to n kun ile laayo la gbọ pe Onidajọ ile ẹjọ naa, Abubakar Sadiq ju sẹwọn oṣu meji pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
yatọ si pe Usman ji Bibeli gbe, wọn tun loo ji fọọmu ati awọn ohun mimu ẹlẹrindodo loriṣiriṣi gbe.

Agbefọba O. S. Ọshọ to foju Usman ba ile ẹjọ sọ pe olori awọn oṣiṣẹ aabo ti ṣọọṣi Living Faith Church, ẹkun Durumi kin-in-ni, David Usman lo mu Usman, to si lọ fa a le awọn ọlọpaa Durumi lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori ẹ.

Bibeli kekere mẹta, Bibeli nla kan, omi onike meji, ohun mimu ẹlẹrindodo ti Caprisonne mẹrinla, iwe ẹri mejidinlogun, fọọmu mẹrinlelọgọfa, aṣọ aabo, aṣọ meji, aṣọ inuju meji, baagi atawọn nnkan miran ni wọn sọ pe Usman jigbe.

A gbọ pe gbogbo awọn nnkan ti Usman jigbe yii lawọn ọlọpaa ti gba pada lọwọ ẹ lakoko iwadii wọn, toun naa si jẹwọ niwaju ile ẹjọ wi pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Onidajọ Abubakar Sadiq, nigba to n gbe idajọ kalẹ, paṣẹ pe ki Usman lọ foju meji gbara lọgba ẹwọn, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, gẹgẹ bi owo itanran, iyẹn ti ko ba fẹẹ ṣẹwọn.

Siwaju sii ni Onidajọ naa fidi rẹ mulẹ pe awọn ko nii foju aanu wo Usman pada, iyẹn bi ọwọ palaba rẹ ba tun segi lori ẹsun ọdaran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI