Ọwọ EFCC tẹ Tijani to n f'iṣẹ ọlọpaa lu jibiti ati ọmọ Yahoo mejilelogoji l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 8, 2023

Ọwọ EFCC tẹ Tijani to n f'iṣẹ ọlọpaa lu jibiti ati ọmọ Yahoo mejilelogoji l'Ogun


Ṣikun bayii lọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹtalelogoji kan loti ẹsun jibiti ori ayelujara.
 
Ẹka ajọ naa tiluu Ibadan la gbọ pe wọn rọwọ to awọn afurasi odaran naa nigboro ilu Ijẹbu-Ode ati Awa Ijẹbu nipinlẹ naa.

Lara wọn ni Tijani Idris Oluwaṣeun, ẹni tiwọn lo n fi kaadi idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa lu awọn araalu ni jibiti kaakiri ilu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun.

Yatọ si Oluwaṣeun, awọn miran tọwọ tẹ ni; Dahud Sodiq Temidayo, Emmanuel Chidibe Peter, Alan Joseph Opeyemi, Sodiq Iyanu Babatunde, Abiodun Olukoya Ibrahim, Adebanjo Oluwaseyi Emmanuel, Olokode Ajibola Obaloluwa, Emiade Azeez Ayotunde, Okeowo Oluwadayo Ahmed, Oludare Abdulazeez Ajadi, Emmanuel Sunday John, Wisdom Alloy, Yusuf Nurudeen, Kadiri Oluwasegun Sodiq, Daniel Christopher Imlegu, Tijani Babatunde, Abubakar Faruq Oluwapelumi, Oyeneye Jerimiah Abiodun, Clement Temitope, Balogun Olatunji, Akinboyede Idris Olawole, Akinlade Gbemileke ati Afeez Lekan.

Awọn miran ni Bankole Timilehin, Akande Olanrewaju, Arowolo Ololade, Kelvin Udanyi, Ayanmo Sunday, Olanusi Bolaji, Victor Ogheneremu, Ogunboye Ayodeji, Emmanuel Ayomide, Ojo Odegbele, Sotunde Tobi, Ayodele Felix, Festus Akindeji, Jonathan Taiwo Resurrection, Agun Michael Okikiola, Olawale Oluwaseyi Ezekiel, Adeife Adeleke, Taiwo Ayanmo ati Aduraja Samuel Olaoluwa. 

Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni mọto bọginni mọkanla, kọmputa alegbeka loriṣiriṣi, iPhones rẹpẹtẹ, aago ibọ ti Apple, ẹyin oni wura ti owo rẹ le ni miliọnu naira.
 
Ajọ EFCC ninu ọrọ wọn ṣalaye pe gbogbo awọn ti aje iwa naa ba ṣi mọ lori ni yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI