Ọmọ 'Yahoo' fi mọto gba iya atọmọ meji danu l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 12, 2023

Ọmọ 'Yahoo' fi mọto gba iya atọmọ meji danu l'Ogun


Niṣe lariwo ikunlẹ abiyamọ sọ laaarọ kutu ọjọ Aiku tii ṣe Sannde, to kọja yii nigba ti wọn sọ pe ọkunrin awakọ kan fi mọto Benz GLX 350 rẹ pa iya atọmọ danu laaarọ kutu ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja lọ lọhun.
 
Adugbo kan ti wọn pe ni Olororo to wa lagbegbe Aiyegbami niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun niṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Wọn nibi t'awọn ọlọpaa ti n le awọn afurasi kan ti wọn jẹ ọmọ Yahoo, ni wọn ti fi mọto naa kọlu iya ati ọmọ rẹ meji, ti wọn si gbabẹ gba ọna ọrun lọ.
 
Ori ọkada la gbọ pe iya ati awọn ọmọ rẹ meji naa wa lasiko iṣẹlẹ ọhun, ti awakọ naa si lọ gba wọn danu.
 
Lara awọn to fi iṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe ẹsẹ ọkan lara awọn ọmọ naa kan danu loju ẹsẹ.
 
Abimbọla Oyeyẹmi nigba to n fesi sọrọ ọhun ṣalaye pe irọ to jinna si otitọ ni pe awọn ọlọpaa n le ọmọ Yahoo lọ, o ni ayederu iroyin pọmbele ni.
 
O sọ pe awakọ naa lo fi mọto rẹ gba mọto awọn ọlọpaa ti wọn gbe sẹgbẹ ọna. O ni nitori ibẹru ki wọn maa mu oun lo jẹ ko gbiyanju lati na papa bora, ati pe nibi to ti n salọ lo jẹ ko wa ọkọ rẹ niwakuwa, to si lọ kọlu iya at'ọmọ meji ti wọn wa lori ọkada
 
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe niṣe ni awakọ ọhun gba ọna ọlọna, to si lọ kọlu mọto awọn ọlọpaa. Ati pe o tun ro pe awọn ọlọpaa naa yoo le oun mu, ṣugbọn ti ko ri bẹẹ.
 
O wa f'idi rẹ mulẹ pe iya at'ọmọ ti wọn n sọ yii, ko si eyi to ku ninu wọn, ati pe wọn wa nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ l'ọsibitu Olabisi Onabanjọ to wa niluu Ṣagamu.
 
Siwaju sii lo sọ pe ọkan lara awọn ọmọ obinrin naa kan lapa, ti ọlọkada to gbe wọn naa si farapa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI