AbdulRazaq, awọn gomina Naijiria ṣepade pẹlu Shettima, Bill Gates ati Dangote (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 23, 2023

AbdulRazaq, awọn gomina Naijiria ṣepade pẹlu Shettima, Bill Gates ati Dangote (Fọto)


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara ti ṣe ipade papọ pẹlu igbakeji aarẹ orileede Naijiria, Kashim Shettima, gbajumọ oniṣowo agbaye nni, Bill Gates, to fi mọ Alaaji Aliko Dangote.
 
Ilu Abuja la gbọ pe ipade ọhun ti waye nibi ti ajọ ẹgbẹ awọn gomina Naijiria ti bu ọla, iyi ati ẹyẹ fun Bill Gates ati Dangote ti wọn n mu eto ọrọ aje agbaye ni ilọsiwaju.
 
Nibẹ ni AbdulRazaq to jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina Naijiria ti gbe oṣuba kare fun Bill Gates ati Dangote, to si ni ipa ti wọn n ko ninu eto ọrọ aje agbaye ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.

Ipade ọhun la gbọ pe wọn gbe kalẹ lati fi mu ki ajọṣepọ to dan mọnran wa laaarin ẹgbẹ awọn gomina pẹlu Bill Gates ati ajọ ileeṣẹ Dangote.
 
AbdulRazaq  ni aṣaaju ati awọkọṣe rere ni Alaaji Dangote fi lelẹ pẹlu bo ṣe n gbaruku ti ọrọ eto ilera, iṣẹ agbẹ ati ọgbin ati idagbasoke, to fi mọ ilọsiwaju ọmọniyan.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI