Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe o ti di eewọ nla bayii fun ẹnikẹni lati da ilẹ tabi gbe ilẹ sẹgbẹ opopona, paapaa awọn agbegbe ti ko yẹ, ti wọn si lẹni tọwọ ba tẹ yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin lẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ ayika ati agbegbe, Yakub Kamaldeen Aliagan fi lede laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe eto igbalegbata yoo waye lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, opin ọsẹ ti a wa yii.
Aliagan ni laaarin agogo meje si mẹsan aarọ, ọjọ kẹrinlelogun ni eto igbalegbata lati fi ṣe imọtoto ayika ati agbegbe kaakiri ipinlẹ naa yoo waye.
Ninu atẹjade ọhun lo ti rọ gbogbo onile ati alejo, paapaa awọn olugbe ipinlẹ naa lati dide si ọrọ eto imọtoto naa, lojuna lati dẹkun ajakalẹ aarun, paapaa lati gbogun ti iṣoro omiyale, agbara ya ṣọọbu.
O ni ẹnikẹni ko gbọdọ ṣi ṣọọbu tabi ta ọja laaarin asiko yii, bẹẹ si ni ko nii si lilọ ati bibọ awọn ọkọ loju popona fun wakati meji naa gbako.
O tẹsiwaju pe awọn alabojuto yoo maa lọ kaakiri lati ṣagbeyẹwo bawọn eeyan ṣe mu ọrọ imọtoto lokukudun lọjọ naa, ati pe awọn mọto to n da ilẹ nu yoo maa lọ kaakiri lati gbe awọn ilẹ t'awọn eeyan ba gba jọ.
No comments:
Post a Comment