AbdulRazaq ṣayẹyẹ June 12 pẹlu awọn ọmọde - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 13, 2023

AbdulRazaq ṣayẹyẹ June 12 pẹlu awọn ọmọde


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara lọjọ Aje, Mọnde ana ti ṣayẹyẹ ayajọ ọjọ eto iṣejọba tiwa-n-tiwa pẹlu awọn ọmọde, paapaa awọn akẹkọọ ile-ẹkọ iranlọwọ ti a mọ si Special Needs.
 
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe akọkọ ree ti Gomina yoo maa ṣabẹwo sile ẹkọ yii, ṣugbọn eyi to waye lanaa jọju pupọ, to si ni ipa rere ni gbesi aye awọn ọmọ naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Nibi abẹwo ọhun ni AbdulRazaq ti lọ ṣagbeyẹwo s'awọn ohun elo ile ẹkọ naa to wa niluu Ilọrin, awọn bii kilaasi, ọfiisi to fi mọ awọn ohun elo amuṣẹrọrun to wa nibẹ.
 
Yatọ si eyi, gomina tun lo anfaani rẹ lati ṣabẹwo si awọn agbegbe ti iji ati agbara ojo to waye laipẹ yii bajẹ, pẹlu ileri wi pe gbogbo rẹ yoo di titunṣe laipẹ jọjọ.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI