Akpabio di Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba Naijiria kẹwaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 13, 2023

Akpabio di Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba Naijiria kẹwaa


Gomina ana nipinlẹ Akwa-Ibom, Godswill Akpabio ni wọn ti dibo yan lati di Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede yii, oun si ni yoo jẹ Aarẹ ile igbimọ naa kẹwaa ti yoo jẹ laaarin ọdun 1999 si asiko yii.
 
Onii, ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee l'awọn aṣofin agba dibo yan Akpabio lati dari wọn nile igbimọ ọhun.
 
Sẹnetọ Akpabio ati gomina tẹlẹri nipinlẹ Zamfara, Abdul-Aziz Yari, la gbọ pe wọn jọ dije du ipo ọhun, ṣugbọn to pada ja mọ Akpabio lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI