Akeredolu gbejọba silẹ fun igbakeji rẹ l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 13, 2023

Akeredolu gbejọba silẹ fun igbakeji rẹ l'Ondo


Gomina Olurotimi Akeredolu ti kọwe sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo lati fi to wọn leti pe igbakeji oun, Lucky Aiyedatiwa ni yoo maa ṣe ijọba ifihẹ titi digba toun yoo pada de lati isinmi eleto ilera toun fẹẹ lọ.
 
Akeredolu sọ pe ọjọ mọkanlelogun loun yoo lọ fi gba itọju nilẹ okeere toun ti fẹ lọ tọju ara oun, to si ni ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu igbakeji gomina naa.
 
Ọnarebu Ọlamide Ọladiji to jẹ abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo lo kede fun gbogbo ile lasiko ijokoo wọn.

Ninu lẹta ti Akeredolu kọ ranṣẹ si wọn lo ti jẹ ko di mimọ pe ọjọ keje, oṣu kẹfa, ọdun 2023 ni ijọba fidihẹ igbakeji oun, Aiyedatiwa ti bẹrẹ, titi di ọjọ kẹfa, oṣu keje, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI