Akpabio/Abass: Awọn aṣofin agba mu oju lọ sọja - AbdulRazaq ba Akpabio, Abass at'awọn yooku yọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 13, 2023

Akpabio/Abass: Awọn aṣofin agba mu oju lọ sọja - AbdulRazaq ba Akpabio, Abass at'awọn yooku yọ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn aṣofin agba orileede Naijiria niluu Abuja mu oju lọ sọja lati yan ẹni to tọ lati di Aarẹ ile igbimọ aṣofin kẹwaa, iyẹn Godswill Akpabio.
 
AbdulRazaq lo sọrọ naa lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita.
 
Nibẹ lo ti ki Sẹnetọ Godswill Akpabio to jawe olubori laaarin awọn meji ti wọn jọ du ipo naa.
 
Bakan naa lo tun ki Onarebu Tajudeen Abass toun naa di abẹnugọn ile igbimọ aṣoju-ṣofin kekere.

Siwaju sii lo tun lo anfaani naa lati ki Sẹnetọ Jibrin Barau ati Onarebu Benjamin Kalu lori b'awọn naa ṣe di igbakeji Aarẹ ile igbimọ aṣofin ati igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣoju-ṣofin.
 
Alaga ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Naijiria naa sọ pe awọn to otọ si ipo naa ni awọn aṣofin ati awọn aṣoju-ṣofin yan lati dari wọn nile igbimọ kẹwaa.

O wa fi kun ọrọ rẹ wi pe oun ti ṣetan lati ba awọn alakoso naa ṣiṣẹ papọ fun ilọsiwaju orileede Naijiria.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI