Alaṣẹ ADRON ba Akpabio, Gbenga Daniel at'awọn aṣofin Naijiria yọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 14, 2023

Alaṣẹ ADRON ba Akpabio, Gbenga Daniel at'awọn aṣofin Naijiria yọ


Alaṣẹ, apaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ
Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing, ti ki Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba kẹwaaa tuntun, Sẹnetọ Godswill Akpabio ati awọn aṣofin agba patapata ku oriire yiyan ti wọn yan wọn.
 
Lara awọn ti Aarẹ EmmanuelKing tun ba yọ ni Sẹnetọ Gbenga Daniel toun naa n ṣoju ẹkun Ogun East nile igbimọ aṣofin ọhun, to si loun nigbagbọ pe wọn yoo ṣe daadaa lasiko yii.
 
Nigba to n ki awọn aṣofin naa ni otẹẹli Nicon Luxury to wa niluu Abuja, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing gbe jade lati fi ki awọn aṣofin ati awọn aṣoju-ṣofin kẹwaa lo ti rọ wọn lati mu ileri wọn ṣẹ, to si loun ṣetan lati ba wọn dowopọ fun igbeleke orileede Naijiria.
 
O loun nigbagbọ pe awọn aṣofin naa yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu, bẹẹ ni wọn yoo jọ ni afojusun kan naa fun ilọsiwaju ati igbelarugẹ orileede Naijiria, paapaa lẹka eto ọrọ aje.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI